Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Infidelity

97 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?

  2. Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀? Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?

  3. Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un, tí kò fi lè ríran; ó sì ń rìn nínú àyíká ọ̀run.

  4. Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí? Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?

  5. O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘Ènìyàn búburú ní ìwọ,’ tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘Ìkà ni ẹ̀yin,’

  6. mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ, nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?

  7. Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọn àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu

  8. tí ó wí pé, “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa; àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?”

  9. Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?

  10. Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”

  11. Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi; iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu, ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,

  12. nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́, wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.

  13. Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i; Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”

  14. Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn; ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?

  15. Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí? Ẹni tí ó dá ojú? Ó ha lè ṣe aláìríran bí?

  16. Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.

  17. Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.

  18. nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,

  19. Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀; wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

  20. Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀, àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,

  21. sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá, jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i, jẹ́ kí ó súnmọ́ bí jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé, kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”

  22. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná, bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku: nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀ wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.

  23. Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀. Àwọn òkè sì wárìrì, òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro. Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀.

  24. “Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́? Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún? Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn, sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.

  25. Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí, ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ; díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”