Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Faith

543 ẹsẹ · 124 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí, èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.

  2. Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ, nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

  3. Kọ ẹkún mi sílẹ̀; kó omijé mi sí ìgò rẹ, wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?

  4. Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́ nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.

  5. Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà. Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

  6. Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.

  7. Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi. Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.

  8. Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ; nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,

  9. Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi. Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi. Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.

  10. Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì? Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?

  11. Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀ tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?

  12. Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn, ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.

  13. Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé; pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

  14. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.

  15. Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.

  16. Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.

  17. Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.

  18. Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi, mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.

  19. nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́. Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní;

  20. àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀, àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.

  21. Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè, ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.

  22. Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi; Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.

  23. Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

  24. Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.

  25. Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.