Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Faith: Enjoined

74 ẹsẹ · 124 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Enjoined

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ kíyèsi i, Olúwa Ọlọ́run yín ló ni ilẹ̀ náà. Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà.”

  2. Nígbà náà ni gbogbo yín tọ̀ mí wá wí pé, “Jẹ́ kí a yan àwọn ayọ́lẹ̀wò láti yọ́ ilẹ̀ náà wò fún wa, kí wọn sì fún wa ní ìròyìn àwọn ọ̀nà tí a ó gbà àti àwọn ìlú tí a ó bá pàdé.”

  3. Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

  4. Wọ́n sì gòkè lọ sí ilẹ̀ òkè náà, wọ́n sì wá sí àfonífojì Eṣkolu, wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò.

  5. Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, “Ilẹ̀ tí ó dára ni Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

  6. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ; ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín.

  7. Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, “Olúwa kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Ejibiti láti fi wá lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wá run.

  8. Níbo la ó lọ? Àwọn arákùnrin wa ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nípa sísọ pé, ‘Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga jù wá lọ; àwọn ìlú náà tóbi jọjọ bẹ́ẹ̀ ni odi wọn ga kan ọ̀run. A tilẹ̀ rí àwọn òmíràn (ìran Anaki) níbẹ̀.’ ”

  9. Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn.

  10. Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín; bí ó ti ṣe fún un yín ní Ejibiti lójú ẹ̀yin tìkára yín

  11. àti ní aginjù. Níbẹ̀ ni ẹ ti rí i bí Olúwa Ọlọ́run yín ti gbé yín, bí baba ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ lọ títí ẹ fi padà dé ibí yìí.”

  12. Ẹ lè máa rò láàrín ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?”

  13. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti.

  14. Ẹ sá à fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. Olúwa Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù.

  15. Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrín wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sá pamọ́ fún un yín, yóò fi ṣègbé.

  16. Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  17. Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ, Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

  18. Nígbà náà ni Mose pe Joṣua ó sì wí fún un níwájú gbogbo Israẹli pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrín wọn bí ogún wọn.

  19. Olúwa fúnra rẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ; kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”

  20. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

  21. “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.

  22. Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.

  23. Má ṣe jẹ́ kí ìwé òfin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.

  24. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

  25. Olúwa sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, “Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará Israẹli sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani. Èmi ni ó ń rán ọ lọ.”