Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Faith

543 ẹsẹ · 124 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́, a kì yóò dójútì mí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.

  2. Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí. Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí? Jẹ́ kí a kojú ara wa! Ta ni olùfisùn mi? Jẹ́ kí ó kò mí lójú!

  3. Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.

  4. “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

  5. Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

  6. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.

  7. Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.

  8. Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà Olúwa.

  9. Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.

  10. Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí Olúwa ti fi fún un.

  11. Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà.

  12. Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

  13. Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.

  14. Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.

  15. Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará Juda.

  16. Wọ́n sọ fún ọba Nebukadnessari pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.

  17. Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà

  18. àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó foríbalẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru.

  19. Ṣùgbọ́n àwọn ará Juda kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agbègbè ìjọba Babeli: Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”

  20. Nígbà náà ni Nebukadnessari pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba.

  21. Nebukadnessari wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀.

  22. Ní ìsinsin yìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetán láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”

  23. Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadnessari, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí.

  24. Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba.

  25. Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”