- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Covetousness
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkígbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsin yìí, pé, ọ̀tá àgbélébùú Kristi ni wọ́n.
Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé.
Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà.
Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá.
àti ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, tiwọn ṣe bí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí.
Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni.
Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ.
Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn.
Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.
Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.
Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù.
Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.”
Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ.
Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.”
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni.
Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.
Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí.
Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.
Ojú wọn kún fún panṣágà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ń tan àwọn tí ọkàn kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ jẹ; àwọn tí wọ́n ní ọkàn tí ó ti yege nínú wọ̀bìà, ọmọ ègún ni wọ́n.
Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ṣáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìṣòdodo.
Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí ìrékọjá rẹ̀, odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì fi òpin sí ìṣiwèrè wòlíì náà.
Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀.
Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé.
Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.