Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Covetousness: Lying

4 ẹsẹ · 49 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Lying

  1. “Gbogbo nǹkan wà dáradára,” Gehasi dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Efraimu. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’ ”

  2. Naamani wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Gehasi láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Gehasi.

  3. Nígbà tí Gehasi sì dé ibi ilé ìṣọ́, ó gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn, ó sì tó wọ́n sínú ilé, ó sì jọ̀wọ́ àwọn ọkùnrin náà lọ́wọ́ lọ, wọ́n sì jáde lọ.

  4. Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Eliṣa. “Níbo ni o ti wà Gehasi?” Eliṣa béèrè. “Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Gehasi dá a lóhùn.