Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ancient Samaria

87 ẹsẹ · 29 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ìjòyè kéékèèké wọ̀nyí ti àwọn ìjòyè ìgbèríko jáde ti ìlú wá, àti ogun tí ó tẹ̀lé wọn.

  2. Olúkúlùkù sì pa ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Àwọn ará Aramu sì sá, Israẹli sì lépa wọn. Ṣùgbọ́n Beni-Hadadi ọba Aramu sì sálà lórí ẹṣin pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin.

  3. Ọba Israẹli sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Aramu ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

  4. Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Naboti ará Jesreeli sì ní ọgbà àjàrà kan ní Jesreeli, ní ẹ̀gbẹ́ ààfin Ahabu ọba Samaria.

  5. Bẹ́ẹ̀ ni ọba kú, a sì gbé e wá sí Samaria, wọ́n sì sin ín ní Samaria.

  6. Wọ́n sì wẹ kẹ̀kẹ́ náà ní adágún Samaria, àwọn ajá sì lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn àgbèrè sì wẹ ara wọn nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti sọ.

  7. Nísinsin yìí Ahasiah ti ṣubú láàrín fèrèsé láti òkè yàrá rẹ̀ tí ó wà ní Samaria, ó sì fi ara pa. Ó sì rán oníṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni, bóyá èmi ó lè rí ìwòsàn ìfarapa yìí.”

  8. Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa wí fún Elijah ará Tiṣibi pé, “Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Samaria kí o sì béèrè lọ́wọ́ wọn, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu òrìṣà Ekroni?’

  9. Ó sì lọ sí orí òkè Karmeli láti ibẹ̀ ó sì padà sí Samaria.

  10. Jehoramu ọmọ Ahabu sì di ọba Israẹli ní Samaria ní ọdún kejìdínlógún ti Jehoṣafati ọba Juda, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjìlá.

  11. Lásìkò ìgbà yìí ọba Jehoramu jáde kúrò ní Samaria ó sì yí gbogbo Israẹli ní ipò padà.

  12. Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

  13. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Beni-Hadadi ọba Aramu kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samaria.

  14. Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú Samaria; wọ́n dúró tí ì tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn-ún.

  15. Gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli ti ń kọjá lọ lórí odi, obìnrin kan sọkún sí i pé, “Ràn mí lọ́wọ́, olúwa ọba mi!”

  16. Ọba sì dá a lóhùn pé, “Bí Olúwa kò bá gbà ọ́, níbo ni èmi yóò gbé ti gbà ọ́? Láti inú ilẹ̀ ìpakà, tàbí láti inú ibi ìfúntí?”

  17. Nígbà náà ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Obìnrin yìí wí fún mi pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ ẹ́ lónìí, ní ọ̀la àwa yóò jẹ ọmọkùnrin tèmi.’

  18. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ọmọkùnrin mi a sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ kejì mo wí fún un pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ,’ ṣùgbọ́n ó ti gbé e pamọ́.”

  19. Nísinsin yìí Eliṣa jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbàgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Eliṣa sọ fún àwọn àgbàgbà pé, “Ṣé ẹ̀yin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dìímú ṣinṣin ní ẹnu-ọ̀nà, ìró ẹsẹ̀ olúwa rẹ̀ kò ha wà lẹ́yìn rẹ?”

  20. Eliṣa wí pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ‘Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, a ó ta òsùwọ̀n ìyẹ̀fun barle kíkúnná kan ní ṣékélì kan àti méjì òsùwọ̀n ọkà barle fún ṣékélì kan ní ẹnu-bodè Samaria.’ ”

  21. Ìjòyè kan ẹni tí ọwọ́ ọba ń fi ara tì dáhùn wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ẹ wò ó, tí Olúwa bá tilẹ̀ ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, ṣé èyí lè rí bẹ́ẹ̀?” Eliṣa dáhùn pé, “Ìwọ yóò rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ nǹkan kan lára rẹ̀!”

  22. nítorí tí Olúwa jẹ́ kí àwọn ará Siria gbọ́ ìró kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin àti ogun ńlá, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, ọba Israẹli ti bẹ ogun àwọn Hiti àti àwọn ọba Ejibiti láti dojúkọ wá!”

  23. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dìde wọ́n sì sálọ ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n sì fi àgọ́ wọn sílẹ̀ àti ẹṣin wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n sì fi ibùdó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, wọ́n sì sálọ fún ẹ̀mí wọn.

  24. Nígbà náà àwọn ènìyàn jáde lọ ìkógun ní ibùdó àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kan ni wọ́n tà fún ṣékélì kan, àti òsùwọ̀n barle méjì ní ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

  25. Nísinsin yìí ọba sì mú ìjòyè náà lórí ẹni tí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ tì ní ìkáwọ́ ẹnu ibodè, àwọn ènìyàn sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè. Ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.