Skip to content

Gozan

5 verses

36.8400, 40.0600 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Gozan

  1. Ní ọdún kẹsànán ti Hosea, ọba Asiria mú Samaria ó sì kó Israẹli lọ sí Asiria. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hala, ní Gosani ní etí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media.

  2. Ọba Asiria lé Israẹli kúrò ní Asiria, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hala, ní Gosani létí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media.

  3. Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá mi gbà wọ́n là: òrìṣà Gosani, Harani Reṣefu àti gbogbo ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari?

  4. Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (èyí ni Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí.

  5. Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gosani, Harani, Reṣefu àti àwọn ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari?