Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ancient Samaria: Deliverance of, effected

7 ẹsẹ · 29 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Deliverance of, effected

  1. Nígbà náà ni Ahabu ka àwọn ìjòyè kéékèèké ìgbèríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (232). Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tókù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000).

  2. Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Beni-Hadadi àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmupara nínú àgọ́.

  3. Àwọn ìjòyè kéékèèké ìgbèríko tètè kọ́ jáde lọ. Beni-Hadadi sì ránṣẹ́ jáde, wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Àwọn ọkùnrin ń ti Samaria jáde wá.”

  4. Ó sì wí pé, “Bí wọ́n bá bá ti àlàáfíà jáde wá, ẹ mú wọn láààyè; bí ti ogun ni wọ́n bá bá jáde, ẹ mú wọn láààyè.”

  5. Àwọn ìjòyè kéékèèké wọ̀nyí ti àwọn ìjòyè ìgbèríko jáde ti ìlú wá, àti ogun tí ó tẹ̀lé wọn.

  6. Olúkúlùkù sì pa ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Àwọn ará Aramu sì sá, Israẹli sì lépa wọn. Ṣùgbọ́n Beni-Hadadi ọba Aramu sì sálà lórí ẹṣin pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin.

  7. Ọba Israẹli sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Aramu ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.