Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Amorites: Intermarry with Jews

29 ẹsẹ · 10 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Intermarry with Jews

  1. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá, wọ́n sì wí pé, “Àwọn ènìyàn Israẹli, tí ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Jebusi, àwọn ará Ammoni, àwọn ará Moabu, àwọn ará Ejibiti àti ti àwọn ará Amori.

  2. Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da irú-ọmọ ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tókù yọ nínú híhu ìwà àìṣòótọ́.”

  3. Lára ìran àwọn àlùfáà àwọn wọ̀nyí fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì. Nínú ìran Jeṣua ọmọ Josadaki, àti àwọn arákùnrin rẹ: Maaseiah, Elieseri, Jaribi àti Gedaliah.

  4. Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìpinnu láti lé àwọn ìyàwó wọn lọ, wọ́n sì fi àgbò kan láàrín agbo ẹran lélẹ̀ fún ẹ̀bi wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀.

  5. Nínú ìran Immeri: Hanani àti Sebadiah.

  6. Nínú ìran Harimu: Maaseiah, Elijah, Ṣemaiah, Jehieli àti Ussiah.

  7. Nínú ìran Paṣuri: Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Netaneli, Josabadi àti Eleasa.

  8. Lára àwọn ọmọ Lefi: Josabadi, Ṣimei, Kelaiah (èyí tí í ṣe Kelita), Petahiah, Juda àti Elieseri.

  9. Nínú àwọn akọrin: Eliaṣibu. Nínú àwọn aṣọ́nà: Ṣallumu, Telemu àti Uri.

  10. Àti lára àwọn ọmọ Israẹli tókù. Nínú ìran Paroṣi: Ramiah, Issiah, Malkiah, Mijamini, Eleasari, Malkiah àti Benaiah.

  11. Nínú ìran Elamu: Mattaniah, Sekariah, Jehieli, Abdi, Jerimoti àti Elijah.

  12. Nínú àwọn ìran Sattu: Elioenai, Eliaṣibu, Mattaniah, Jerimoti, Sabadi àti Asisa.

  13. Nínú àwọn ìran Bebai: Jehohanani, Hananiah, Sabbai àti Atlai.

  14. Nínú àwọn ìran Bani: Meṣullamu, Malluki, Adaiah, Jaṣubu, Ṣeali àti Jerimoti.

  15. Nínú àwọn Pahati-Moabu: Adma, Kelali, Benaiah, Maaseiah, Mattaniah, Besaleli, Binnui àti Manase.

  16. Nínú àwọn ìran Harimu: Elieseri, Iṣiah, Malkiah àti Ṣemaiah, Simeoni,

  17. Benjamini, Malluki àti Ṣemariah.

  18. Nínú àwọn ìran Haṣumu: Mattenai, Mattatta, Sabadi, Elifaleti, Jeremai, Manase àti Ṣimei.

  19. Nínú àwọn ìran Bani: Maadai, Amramu, Ueli,

  20. Benaiah, Bediah, Keluhi

  21. Faniah, Meremoti, Eliaṣibu,

  22. Mattaniah, Mattenai àti Jaasu.

  23. Àti Bani, àti Binnui: Ṣimei,

  24. Ṣelemiah, Natani, Adaiah,

  25. Maknadebai, Sasai, Ṣarai,