Fò sí àkóónú

circa AD 95

The Revelation

John's vision on Patmos unveils the cosmic victory of the Lamb over evil and the final restoration of all creation.

404 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìfihàn 6:5nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, “Wá wò ó”. Mo sì wò ó, sì kíyèsi i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀.

  2. Ìfihàn 6:6nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òsùwọ̀n alikama kan fún owó idẹ kan, àti òsùwọ̀n ọkà barle mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsi i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.

  3. Ìfihàn 6:7nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, “Wá wò ó!”

  4. Ìfihàn 6:8nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹṣin ràndànràndàn kan, orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdámẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa.

  5. Ìfihàn 6:9nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú,

  6. Ìfihàn 6:10nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?”

  7. Ìfihàn 6:11nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí a o pa bí wọn, yóò fi dé.

  8. Ìfihàn 6:12nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀;

  9. Ìfihàn 6:13nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í.

  10. Ìfihàn 6:14nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.

  11. Ìfihàn 6:15nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè;

  12. Ìfihàn 6:16nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.

  13. Ìfihàn 6:17nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn dé; ta ni ó sì le dúró?”

  14. Ìfihàn 7:1nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn èyí ni mo rí angẹli mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí Òkun, tàbí sára igikígi.

  15. Ìfihàn 7:2nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára,

  16. Ìfihàn 7:3nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.”

  17. Ìfihàn 7:4nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si, àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá.

  18. Ìfihàn 7:5nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Láti inú ẹ̀yà Juda a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Reubeni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Gadi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).

  19. Ìfihàn 7:6nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Láti inú ẹ̀yà Aṣeri a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Naftali a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Manase a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).

  20. Ìfihàn 7:7nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Láti inú ẹ̀yà Simeoni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Lefi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Isakari a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).

  21. Ìfihàn 7:8nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Josẹfu a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Benjamini a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).

  22. Ìfihàn 7:9nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn.

  23. Ìfihàn 7:10nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé: “Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá tí o jókòó lórí ìtẹ́, àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!”

  24. Ìfihàn 7:11nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run.

  25. Ìfihàn 7:12nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Wí pe: “Àmín! Ìbùkún, àti ògo, àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá, àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé! Àmín!”