Fò sí àkóónú

circa AD 95

The Revelation

John's vision on Patmos unveils the cosmic victory of the Lamb over evil and the final restoration of all creation.

404 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìfihàn 13:15nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà.

  2. Ìfihàn 13:16nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba àmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn;

  3. Ìfihàn 13:17nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní àmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí àmì orúkọ rẹ̀.

  4. Ìfihàn 13:18nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Níhìn-ín ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka òǹkà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà, nítorí pé òǹkà ènìyàn ni, òǹkà rẹ̀ náà sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666).

  5. Ìfihàn 14:1nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.

  6. Ìfihàn 14:2nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá, mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù.

  7. Ìfihàn 14:3nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ náà, àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin n nì àti àwọn àgbà náà, kò sì ṣí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá.

  8. Ìfihàn 14:4nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí, nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.

  9. Ìfihàn 14:5nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.

  10. Ìfihàn 14:6nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìyìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.

  11. Ìfihàn 14:7nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”

  12. Ìfihàn 14:8nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Angẹli mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “o ṣubú, Babeli ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”

  13. Ìfihàn 14:9nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀.

  14. Ìfihàn 14:10nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn.

  15. Ìfihàn 14:11nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.”

  16. Ìfihàn 14:12nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.

  17. Ìfihàn 14:13nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.” Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”

  18. Ìfihàn 14:14nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀.

  19. Ìfihàn 14:15nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.”

  20. Ìfihàn 14:16nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.

  21. Ìfihàn 14:17nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan.

  22. Ìfihàn 14:18nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Angẹli mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ́ àwọn ìdì àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.”

  23. Ìfihàn 14:19nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Angẹli náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ̀ ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntí, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run.

  24. Ìfihàn 14:20nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ (1,600) ibùsọ̀.

  25. Ìfihàn 15:1nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì rí àmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn angẹli méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹyìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin.