- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 95
The Revelation
John's vision on Patmos unveils the cosmic victory of the Lamb over evil and the final restoration of all creation.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Ìfihàn 11:1nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
A sì fi ìfèéfèé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá-ìwọ̀n: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹmpili Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀.
- Ìfihàn 11:2nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì (42).
- Ìfihàn 11:3nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó lé ọgọ́ta (1,260) nínú aṣọ ọ̀fọ̀.”
- Ìfihàn 11:4nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Wọ̀nyí ni igi olifi méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé.
- Ìfihàn 11:5nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lára, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀tá wọn run, báyìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run.
- Ìfihàn 11:6nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn. Wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-ààrùn kọlu ayé, nígbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́.
- Ìfihàn 11:7nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n.
- Ìfihàn 11:8nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sodomu àti Ejibiti nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú.
- Ìfihàn 11:9nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì.
- Ìfihàn 11:10nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró.
- Ìfihàn 11:11nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹsẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn.
- Ìfihàn 11:12nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀; lójú àwọn ọ̀tá wọn.
- Ìfihàn 11:13nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ní wákàtí náà omìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ́wàá ìlú náà sì wó, àti nínú omìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.
- Ìfihàn 11:14nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ègbé kejì kọjá; sì kíyèsi i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán.
- Ìfihàn 11:15nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, “Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀; òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”
- Ìfihàn 11:16nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run,
- Ìfihàn 11:17nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
wí pé: “Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè, tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀, ìwọ sì ti jẹ ọba.
- Ìfihàn 11:18nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé, àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́, àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì, àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀, àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá; àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”
- Ìfihàn 11:19nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
A sì ṣí tẹmpili Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mú nínú tẹmpili rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ̀ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.
- Ìfihàn 12:1nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àmì ńlá kan sì hàn ni ọ̀run; obìnrin kan tí a fi oòrùn wọ̀ ní aṣọ, òṣùpá sì ń bẹ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá sì ń bẹ lórí rẹ̀.
- Ìfihàn 12:2nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ó sì lóyún, ó sì kígbe ni ìrọbí, ó sì wà ni ìrora àti bímọ.
- Ìfihàn 12:3nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àmì mìíràn sì hàn ní ọ̀run; sì kíyèsi i, dragoni pupa ńlá kan, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, àti adé méje ní orí rẹ̀.
- Ìfihàn 12:4nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ìrù rẹ̀ sì wọ́ ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run, ó sì jù wọ́n sí ilẹ̀ ayé, dragoni náà sì dúró níwájú obìnrin náà tí ó fẹ́ bímọ, pé nígbà tí o bá bí i, kí òun lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ.
- Ìfihàn 12:5nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ó sì bi ọmọkùnrin kan tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, a sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sókè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí orí ìtẹ́ rẹ̀.
- Ìfihàn 12:6nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Obìnrin náà sì sálọ sí aginjù, níbi tí a gbé ti pèsè ààyè sílẹ̀ dè é láti ọwọ́ Ọlọ́run wá, pé kí wọ́n máa bọ́ ọ níbẹ̀ ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó lé ọgọ́ta (1,260).