circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 12:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé, pé nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán.
- Luku 12:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
- Luku 12:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà.
- Luku 12:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí tí olè yóò wá, òun ìbá máa ṣọ́nà, kì bá tí jẹ́ kí a já wọ inú ilé òun.
- Luku 12:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, kí ẹ̀yin múra pẹ̀lú, nítorí Ọmọ Ènìyàn ń bọ̀ ní wákàtí tí ẹ̀yin kò nírètí.”
- Luku 12:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Peteru sì wí pé, “Olúwa, ìwọ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn?”
- Luku 12:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Olúwa sì dáhùn wí pé, “Ta ni olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ́n fún wọn ní àkókò?
- Luku 12:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ìbùkún ni fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nígbà tí olúwa rẹ̀ bá dé, tí yóò bá a kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.
- Luku 12:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lóòótọ́ ni mo wí fún yín yóò fi jẹ olórí ohun gbogbo tí ó ní.
- Luku 12:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá wí ní ọkàn rẹ̀, pé, ‘Olúwa mi fi ìgbà bíbọ̀ rẹ̀ falẹ̀!’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àti sí mu àmupara:
- Luku 12:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ ní yà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.
- Luku 12:47nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Àti ọmọ ọ̀dọ̀ náà, tí ó mọ ìfẹ́ olúwa rẹ̀, tí kò sì múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, òun ni a ó nà púpọ̀.
- Luku 12:48nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé béèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé béèrè sí i.
- Luku 12:49nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Iná ni èmi wá láti sọ sí ayé; kín ni èmi sì ń fẹ́ bí kò ṣe kí iná náà ti jo!
- Luku 12:50nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n èmi ní bamitiisi kan tí a ó fi bamitiisi mi; ara ti ń ni mí tó títí yóò fi parí!
- Luku 12:51nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin ṣe bí àlàáfíà ni èmi fi sí ayé? Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n bí kò ṣe ìyapa.
- Luku 12:52nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí láti ìsinsin yìí lọ, ènìyàn márùn-ún yóò wà ní ilé kan náà tí a ó yà ní ipa, mẹ́ta sí méjì, àti méjì sí mẹ́ta.
- Luku 12:53nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
A ó ya baba nípa sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọkùnrin sí baba; ìyá sí ọmọbìnrin, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ, àti ìyàwó ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀.”
- Luku 12:54nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pẹ̀lú pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá rí àwọsánmọ̀ tí ó ṣú ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, lọ́gán ni ẹ̀yin yóò sọ pé, ‘Ọ̀wààrà òjò ń bọ̀,’ a sì rí bẹ́ẹ̀.
- Luku 12:55nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù bá ń fẹ́, ẹ̀yin á ní, ‘Oòrùn yóò mú,’ yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀.
- Luku 12:56nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin le mòye ojú ọ̀run àti ti ayé. Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò mọ àkókò yìí?
- Luku 12:57nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin tìkára yín kò fi ro ohun tí ó tọ́?
- Luku 12:58nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ìwọ bá bá ọ̀tá rẹ lọ sọ́dọ̀ onídàájọ́, rí i pé o bá a parí ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà kí ó má ba à fà ọ́ fún adájọ́, adájọ́ a fi ọ́ lé ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, òun a sì tì ọ́ sínú túbú.
- Luku 12:59nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kí èmi wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀, títí ìwọ ó fi san ẹyọ owó kan tí ó kù!”
- Luku 13:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Galili fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pilatu dàpọ̀ mọ́ ẹbọ wọn.