circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 11:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú?
- Luku 11:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín.
- Luku 11:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.
- Luku 11:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú Sinagọgu, àti ìkíni ní ọjà.
- Luku 11:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ègbé ni fún un yín,nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.”
- Luku 11:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú.”
- Luku 11:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí pé, “Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkára yín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà.
- Luku 11:47nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa.
- Luku 11:48nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn.
- Luku 11:49nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì ṣe wí pé, ‘Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn aposteli sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.’
- Luku 11:50nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí;
- Luku 11:51nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí.
- Luku 11:52nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin amòfin, nítorí tí ẹ̀yin ti mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ kúrò; ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, àwọn tí sì ń wọlé, ni ẹ̀yin ń dí lọ́wọ́.”
- Luku 11:53nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí ó ti ń lọ kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bi í lọ́rọ̀ gidigidi, wọ́n sì ń yọ ọ́ lẹ́nu láti wí nǹkan púpọ̀.
- Luku 11:54nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n ń ṣọ́ ọ, wọ́n ń wá ọ̀nà láti rí nǹkan gbámú lẹ́nu kí wọn bá à lè fi ẹ̀sùn kàn án.
- Luku 12:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sísọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa ṣọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi tí í ṣe àgàbàgebè.
- Luku 12:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀.
- Luku 12:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní iyàrá, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀.
- Luku 12:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́.
- Luku 12:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù.
- Luku 12:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ológoṣẹ́ márùn-ún sá à ni a ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run?
- Luku 12:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ̀yin ní iye lórí ju ológoṣẹ́ púpọ̀ lọ.
- Luku 12:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ Ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run.
- Luku 12:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú ènìyàn, a ó sẹ́ ẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run.
- Luku 12:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ọmọ Ènìyàn, a ó dárí rẹ̀ jì í; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jì í.