Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Luku 11:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Beelsebulu olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

  2. Luku 11:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ àmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá.

  3. Luku 11:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n òun mọ èrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di ahoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó.

  4. Luku 11:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí Satani ba yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.

  5. Luku 11:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó ba ṣe pé nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, nípa ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídàájọ́ yín.

  6. Luku 11:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé nípa ìka ọwọ́ Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán.

  7. Luku 11:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ni ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà.

  8. Luku 11:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀.

  9. Luku 11:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi, ẹni tí kò bá sì bá mi kójọpọ̀, ó fọ́nká.

  10. Luku 11:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ bá jáde kúrò lára ènìyàn, a máa rìn kiri ní ibi gbígbẹ, a máa wá ibi ìsinmi; nígbà tí kò bá sì rí, a wí pé, ‘Èmi yóò padà lọ sí ilé mi ní ibi tí mo gbé ti jáde wá.’

  11. Luku 11:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó bá sì dé, tí ó sì rí tí a gbá a, tí a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́.

  12. Luku 11:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun tìkára rẹ̀ lọ wá, wọn yóò wọlé, wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀, ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà yóò sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.”

  13. Luku 11:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”

  14. Luku 11:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”

  15. Luku 11:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí, wọ́n ń wá àmì; a kì yóò sì fi àmì kan fún un bí kò ṣe àmì Jona wòlíì!

  16. Luku 11:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí bí Jona ti jẹ́ àmì fún àwọn ará Ninefe, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ Ènìyàn yóò ṣe jẹ́ àmì fún ìran yìí.

  17. Luku 11:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọbabìnrin gúúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni lọ ń bẹ níhìn-ín yìí.

  18. Luku 11:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ará Ninefe yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona; sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Jona lọ ń bẹ níhìn-ín yìí.

  19. Luku 11:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òsùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé ba à lè máa rí ìmọ́lẹ̀.

  20. Luku 11:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ojú ni fìtílà ara: bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ a mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá ṣókùnkùn, ara rẹ pẹ̀lú a kún fún òkùnkùn.

  21. Luku 11:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà kíyèsi i, kí ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ má ṣe di òkùnkùn.

  22. Luku 11:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apá kan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànṣán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”

  23. Luku 11:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó sì ti ń wí, Farisi kan bẹ̀ ẹ́ kí ó bá òun jẹun: ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun.

  24. Luku 11:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Farisi náà sì rí i, ẹnu yà á nítorí tí kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ kí ó tó jẹun.

  25. Luku 11:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Olúwa sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa ń fọ òde ago àti àwopọ̀kọ́: ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ.