circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 13:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
- Luku 13:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.
- Luku 13:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti ìwọ̀-oòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run.
- Luku 13:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni iwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”
- Luku 13:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisi tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhìn-ín yìí: nítorí Herodu ń fẹ́ pa ọ́.”
- Luku 13:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’
- Luku 13:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lónìí, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: dájúdájú wòlíì kan ki yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerusalẹmu.
- Luku 13:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!
- Luku 13:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”
- Luku 14:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisi lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ.
- Luku 14:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ó ní ara wíwú níwájú rẹ̀.
- Luku 14:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisi pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbí kò tọ́?”
- Luku 14:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
- Luku 14:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?”
- Luku 14:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.
- Luku 14:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé,
- Luku 14:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ.
- Luku 14:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní ààyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn.
- Luku 14:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó ti oúnjẹ.
- Luku 14:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbéga.”
- Luku 14:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà.
- Luku 14:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú:
- Luku 14:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ, ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.”
- Luku 14:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!”
- Luku 14:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀.