circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 1:27nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
sí wúńdíá kan tí a ṣèlérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Josẹfu, ti ìdílé Dafidi; orúkọ wúńdíá náà a sì máa jẹ́ Maria.
- Luku 1:28nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.”
- Luku 1:29nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ọkàn Maria kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kín ni èyí.
- Luku 1:30nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
- Luku 1:31nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu.
- Luku 1:32nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Òun ó pọ̀, ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é, Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún.
- Luku 1:33nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Yóò sì jẹ ọba lórí ilé Jakọbu títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”
- Luku 1:34nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Maria béèrè lọ́wọ́ angẹli náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tí ì mọ ọkùnrin.”
- Luku 1:35nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Angẹli náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò síji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é.
- Luku 1:36nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Sì kíyèsi i, Elisabeti ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọkùnrin kan ní ògbólógbòó rẹ̀, èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn.
- Luku 1:37nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”
- Luku 1:38nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
- Luku 1:39nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea;
- Luku 1:40nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó sì wọ ilé Sekariah lọ ó sì kí Elisabeti.
- Luku 1:41nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́,
- Luku 1:42nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkún fún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí.
- Luku 1:43nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá?
- Luku 1:44nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀.
- Luku 1:45nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Alábùkún fún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́, nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”
- Luku 1:46nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Maria sì dáhùn, ó ní: “Ọkàn mi yin Olúwa lógo.
- Luku 1:47nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
- Luku 1:48nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Nítorí tí ó síjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀. Sá wò ó, láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
- Luku 1:49nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi; Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
- Luku 1:50nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, láti ìrandíran.
- Luku 1:51nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀; o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.