circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 1:52nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn, o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
- Luku 1:53nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
- Luku 1:54nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́, ní ìrántí àánú rẹ̀;
- Luku 1:55nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa, àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
- Luku 1:56nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Maria sì jókòó tì Elisabeti níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.
- Luku 1:57nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọjọ́ Elisabeti pé tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan.
- Luku 1:58nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.
- Luku 1:59nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sekariah, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀.
- Luku 1:60nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Johanu ni a ó pè é.”
- Luku 1:61nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”
- Luku 1:62nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é.
- Luku 1:63nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn.
- Luku 1:64nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run.
- Luku 1:65nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn, a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Judea.
- Luku 1:66nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó sì jẹ́ ohun ìyanu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì tò ó sínú ọkàn wọn, wọ́n ń wí pé, “Irú-ọmọ kín ni èyí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
- Luku 1:67nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní:
- Luku 1:68nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
“Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli; nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
- Luku 1:69nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa ní ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀;
- Luku 1:70nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
(bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),
- Luku 1:71nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá.
- Luku 1:72nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
Láti ṣe àánú tí ó ṣèlérí fún àwọn baba wa, àti láti rántí májẹ̀mú rẹ̀ mímọ́,
- Luku 1:73nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa,
- Luku 1:74nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, kí àwa kí ó lè máa sìn láìfòyà,
- Luku 1:75nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
ni ìwà mímọ́ àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
- Luku 1:76nǹkan bí 5 ṣáájú Kristi
“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́: nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;