circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Matiu 15:37nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Gbogbo wọn jẹ, wọ́n sì yó. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì ṣa èyí tókù, ẹ̀kún agbọ̀n méje ni èyí tó ṣẹ́kù jẹ́.
- Matiu 15:38nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Gbogbo wọn sì jẹ́ ẹgbàajì (4,000) ọkùnrin láì kan àwọn obìnrin àti ọmọdé.
- Matiu 15:39nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn náà, Jesu rán àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé wọn, ó sì bọ́ sínú ọkọ̀, ó rékọjá lọ sí ẹkùn Magadani.
- Matiu 16:1nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Àwọn Farisi àti àwọn Sadusi wá láti dán Jesu wò. Wọ́n ní kí ó fi àmì ńlá kan hàn àwọn ní ojú ọ̀run.
- Matiu 16:2nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ó bá di àṣálẹ́, ẹ ó sọ pé, ‘Ìbá dára kí ojú ọ̀run pọ́n.’
- Matiu 16:3nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ní òwúrọ̀, ‘Ẹ̀yin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ àmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ àmì àwọn àkókò wọ̀nyí.
- Matiu 16:4nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè àmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkankan ní àmì bí kò ṣe àmì Jona.” Nígbà náà ni Jesu fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ.
- Matiu 16:5nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́.
- Matiu 16:6nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisi àti àwọn Sadusi.”
- Matiu 16:7nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárín ara wọn wí pé, “Nítorí tí àwa kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni.”
- Matiu 16:8nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́?
- Matiu 16:9nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsin yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìṣù àkàrà márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kójọ bí àjẹkù?
- Matiu 16:10nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ẹ kò sì tún rántí ìṣù méje tí mo fi bọ́ ẹgbàajì (4,000) ènìyàn àti iye agbọ̀n tí ẹ̀yín kójọ?
- Matiu 16:11nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Èéha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti àkàrà? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi àti ti Sadusi.”
- Matiu 16:12nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyèsára, bí kò ṣe tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisi àti Sadusi.
- Matiu 16:13nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Jesu sì dé Kesarea-Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ Ènìyàn pè?”
- Matiu 16:14nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Johanu onítẹ̀bọmi ni, àwọn mìíràn wí pé, Elijah ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremiah ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”
- Matiu 16:15nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
“Ṣùgbọ́n ẹyin ń kọ?” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mi pè?”
- Matiu 16:16nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Simoni Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”
- Matiu 16:17nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì wí fún un pé, “Alábùkún fún ni ìwọ Simoni ọmọ Jona, nítorí ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ló fi èyí hàn bí kò ṣe Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.
- Matiu 16:18nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀.
- Matiu 16:19nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.”
- Matiu 16:20nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kristi náà.
- Matiu 16:21nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Láti ìgbà yìí lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerusalẹmu láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé, kí a sì pa òun, àti ní ọjọ́ kẹta, kí ó sì jíǹde.
- Matiu 16:22nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Peteru mú Jesu sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé, “Kí a má rí i Olúwa! Èyí kì yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọ!”