circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Matiu 15:12nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé inú bí àwọn Farisi lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ yìí?”
- Matiu 15:13nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fàtu tigbòǹgbò tigbòǹgbò,
- Matiu 15:14nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”
- Matiu 15:15nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Peteru wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”
- Matiu 15:16nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”?
- Matiu 15:17nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
“Ẹyin kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde?
- Matiu 15:18nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́.
- Matiu 15:19nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.
- Matiu 15:20nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́. Ṣùgbọ́n láti jẹun láì wẹ ọwọ́, kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́.”
- Matiu 15:21nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì ti ibẹ̀ kúrò lọ sí Tire àti Sidoni.
- Matiu 15:22nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Obìnrin kan láti Kenaani, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.”
- Matiu 15:23nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n Jesu kò fún un ní ìdáhùn, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á níyànjú pé, “Lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”
- Matiu 15:24nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Israẹli tí ó nù nìkan ni a rán mi sí.”
- Matiu 15:25nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.”
- Matiu 15:26nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
- Matiu 15:27nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èrúnrún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”
- Matiu 15:28nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ láradá ní wákàtí kan náà.
- Matiu 15:29nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu ti ibẹ̀ lọ sí Òkun Galili. Ó gun orí òkè, o sì jókòó níbẹ̀.
- Matiu 15:30nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúnkùn ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. Òun sì mú gbogbo wọn láradá.
- Matiu 15:31nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Ẹnu ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúnkùn ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran. Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Israẹli.
- Matiu 15:32nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó wí pé, “Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí; nítorí wọ́n ti wà níhìn-ín pẹ̀lú mi fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko báyìí. Wọn kò sì tún ní oúnjẹ mọ́. Èmi kò fẹ́ kí wọn padà lébi, nítorí òyì lè kọ́ wọn lójú ọ̀nà.”
- Matiu 15:33nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, “Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ijù níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí?”
- Matiu 15:34nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ní?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa ní ìṣù àkàrà méje pẹ̀lú àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.”
- Matiu 15:35nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀.
- Matiu 15:36nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi
Òun sì mú ìṣù àkàrà méje náà àti ẹja náà. Ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó bù wọ́n sì wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì pín in fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà.