Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Matiu 14:23nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnra rẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀,

  2. Matiu 14:24nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.

  3. Matiu 14:25nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi.

  4. Matiu 14:26nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni,” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.

  5. Matiu 14:27nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

  6. Matiu 14:28nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”

  7. Matiu 14:29nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.” Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu.

  8. Matiu 14:30nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”

  9. Matiu 14:31nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”

  10. Matiu 14:32nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́.

  11. Matiu 14:33nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”

  12. Matiu 14:34nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn rékọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti.

  13. Matiu 14:35nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá.

  14. Matiu 14:36nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.

  15. Matiu 15:1nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ní àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jesu wá láti Jerusalẹmu,

  16. Matiu 15:2nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    wọn béèrè pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń rú òfin àtayébáyé àwọn alàgbà? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”

  17. Matiu 15:3nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín?

  18. Matiu 15:4nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àti pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.’

  19. Matiu 15:5nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, ‘Ẹ̀bùn fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi,’

  20. Matiu 15:6nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ òfin Ọlọ́run di asán nípa àṣà yín.

  21. Matiu 15:7nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

  22. Matiu 15:8nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.

  23. Matiu 15:9nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Lásán ni ìsìn wọn; nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

  24. Matiu 15:10nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, “Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín.

  25. Matiu 15:11nǹkan bí 32 lẹ́yìn Kristi

    Ènìyàn kò di aláìmọ́ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ní di aláìmọ́.”