- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1380–1050 BC
The Judges & Ruth
Israel cycles through rebellion, oppression, and rescue under charismatic leaders—culminating in Ruth's faithful love story.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Rutu 2:11nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí.
- Rutu 2:12nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Kí Olúwa kí ó san ẹ̀san ohun tí ìwọ ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.”
- Rutu 2:13nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Rutu sì fèsì wí pé, “Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ síwájú sí i olúwa mi. Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.”
- Rutu 2:14nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Boasi sọ fún Rutu pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yìí kí o sì fi run wáìnì kíkan.” Òun sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Boasi sì fún un ní ọkà yíyan. Òun sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù.
- Rutu 2:15nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣá ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàrín oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́.
- Rutu 2:16nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Bí kò ṣe pé kí ẹ mú lára àwọn ìtí sílẹ̀ fún láti ṣá, kí ẹ má sì ṣe ba a wí.”
- Rutu 2:17nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Rutu sì ń ṣá ọkà títí ó fi di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ó sì pa ọkà barle tí ó rí ṣà, tí ó sì fẹ́ ẹ tán, èyí tí ó rí sì tó ìwọ̀n garawa kan (lita méjìlélógún).
- Rutu 2:18nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Ó sì gbé e, ó sì lọ sí ìlú, ìyá ọkọ rẹ sì rí ọkà tí ó rí ṣà bi o tí pọ̀ tó, Rutu sì mú oúnjẹ tí ó jẹ kù lẹ́yìn tí ó ti yó tan fún ìyá ọkọ rẹ̀.
- Rutu 2:19nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, “Níbo ni ìwọ ti ṣá ọkà lónìí? Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́? Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ.” Rutu sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, “Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi ni mo ti ṣiṣẹ́ lónìí.”
- Rutu 2:20nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Naomi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Naomi sì sọ síwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní ìdílé padà.”
- Rutu 2:21nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Rutu, ará Moabu sì wí pé, “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, ‘Kí ń máa ṣá ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè.’ ”
- Rutu 2:22nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Naomi sì sọ fún Rutu, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.”
- Rutu 2:23nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Rutu sì bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin Boasi ṣiṣẹ́ títí tí wọ́n fi parí ìkórè ọkà barle àti ti jéró. Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀.
- Rutu 3:1nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kan, Naomi, ìyá ọkọ Rutu wí fún un pé, “Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ?
- Rutu 3:2nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Wò ó, Boasi ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà barle ní ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí.
- Rutu 3:3nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Wẹ̀, kí o sì fi ìpara olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán.
- Rutu 3:4nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o ṣí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.”
- Rutu 3:5nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Rutu sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”
- Rutu 3:6nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Rutu lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un, pé kí o ṣe.
- Rutu 3:7nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Boasi parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà tí wọ́n kójọ. Rutu yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.
- Rutu 3:8nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárín òru, ẹ̀rù bà á, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.
- Rutu 3:9nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?” Rutu sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rutu, ìránṣẹ́bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.”
- Rutu 3:10nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Boasi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà.
- Rutu 3:11nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́n ní obìnrin oníwà rere.
- Rutu 3:12nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Nítòótọ́ ni mo wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó súnmọ́ ọ ju ti tèmi lọ.