- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1380–1050 BC
The Judges & Ruth
Israel cycles through rebellion, oppression, and rescue under charismatic leaders—culminating in Ruth's faithful love story.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Rutu 1:8nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Naomi wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, “Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú.
- Rutu 1:9nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Kí Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn.” Naomi sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé “Ó dìgbà,” wọ́n sì sọkún kíkankíkan.
- Rutu 1:10nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì wí fún un pé, “Rárá, a ó bà ọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”
- Rutu 1:11nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Naomi dáhùn wí pé, “Ẹ padà sílé ẹ̀yin ọmọ mi. Nítorí kí ni ẹ fi fẹ́ wá pẹ̀lú mi? Ṣé mo tún le bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn ni, tí ó le ṣe ọkọ yin?
- Rutu 1:12nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Ẹ padà sílé, ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí èmi ti di arúgbó jù láti ní ọkọ mìíràn. Bí èmí wí pé, èmí ní ìrètí, bí èmí tilẹ̀ ní ọkọ mìíràn ní alẹ́ yìí, tí èmí sì bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn,
- Rutu 1:13nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
ẹ̀yin ha le è dúró dìgbà tí wọ́n yóò fi dàgbà? Ẹ̀yin ó le è dúró dè wọ́n láì fẹ́ ọkọ mìíràn? Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, nítorí pé inú mi bàjẹ́ gidigidi ju tiyín lọ, nítorí tí ọwọ́ Olúwa fi jáde sí mi!”
- Rutu 1:14nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì tún sọkún. Nígbà náà ní Oripa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rutu dì mọ́ ọn síbẹ̀.
- Rutu 1:15nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Naomi wí pé, “Wò ó, arábìnrin rẹ ti padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti òrìṣà rẹ̀, ìwọ náà padà pẹ̀lú rẹ̀.”
- Rutu 1:16nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Rutu dáhùn wí pé, “Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ. Ibi tí ìwọ bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ìwọ bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.
- Rutu 1:17nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Níbi tí ìwọ bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí. Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá.”
- Rutu 1:18nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Naomi rí i wí pé Rutu ti pinnu láti tẹ̀lé òun kò rọ̀ láti padà mọ́.
- Rutu 1:19nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé ìlú Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ariwo ìpadàbọ̀ wọn gba ìlú kan, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Naomi ni èyí bí?”
- Rutu 1:20nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Naomi sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Naomi mọ́, ẹ pè mí ní Mara, nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò.
- Rutu 1:21nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n Olúwa mú mi padà ní òfo. Nítorí náà kín ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi?”
- Rutu 1:22nǹkan bí 1308 ṣáájú Kristi
Báyìí ni Naomi ṣe padà láti Moabu pẹ̀lú Rutu, ará Moabu ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹtilẹhẹmu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà barle.
- Rutu 2:1nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Naomi ní ìbátan kan láti ìdílé Elimeleki ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi.
- Rutu 2:2nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Rutu ará Moabu sì wí fún Naomi pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojúrere rẹ̀ pàdé.” Naomi sì sọ fún un pé, “Máa lọ, ọmọbìnrin mi.”
- Rutu 2:3nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Rutu sì jáde lọ láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn. Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Boasi tí ó ti ìdílé Elimeleki wá ni ó lọ láìmọ̀-ọ́n-mọ̀.
- Rutu 2:4nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Boasi dé láti Bẹtilẹhẹmu tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí Olúwa wà pẹ̀lú yín.” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ.”
- Rutu 2:5nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Boasi sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, “Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn?”
- Rutu 2:6nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, “Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Moabu tí ó tẹ̀lé Naomi wá láti ilẹ̀ Moabu ni.
- Rutu 2:7nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Ó sọ wí pé, ‘Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣá ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè.’ Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsin yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì.”
- Rutu 2:8nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Boasi sọ fún Rutu pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣá ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi.
- Rutu 2:9nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkígbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.”
- Rutu 2:10nǹkan bí 1307 ṣáájú Kristi
Rutu wólẹ̀, ó sì wí fún Boasi pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsi mi, èmi àjèjì àti àlejò?”