circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 5:22nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí. “Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí? Mo fi yanrìn pààlà òkun, èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé. Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀; wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.
- Jeremiah 5:23nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀, wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.
- Jeremiah 5:24nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Wọn kò sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀, tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’
- Jeremiah 5:25nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.
- Jeremiah 5:26nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ, àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.
- Jeremiah 5:27nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ, ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn; wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,
- Jeremiah 5:28nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
wọ́n sanra wọ́n sì ń dán. Ìwà búburú wọn kò sì lópin; wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀. Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.
- Jeremiah 5:29nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?
- Jeremiah 5:30nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtara ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà.
- Jeremiah 5:31nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn, àwọn ènìyàn mi sì ní ìfẹ́ sí èyí, kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?
- Jeremiah 6:1nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu. Ẹ fọn fèrè ní Tekoa! Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Beti-Hakeremu! Nítorí àjálù farahàn láti àríwá, àní ìparun tí ó lágbára.
- Jeremiah 6:2nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run, tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.
- Jeremiah 6:3nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n. Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká, olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”
- Jeremiah 6:4nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán! Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.
- Jeremiah 6:5nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́ kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”
- Jeremiah 6:6nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀ kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká. Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò, nítorí pé ó kún fún ìninilára.
- Jeremiah 6:7nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀, náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde. Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀; nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.
- Jeremiah 6:8nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀, kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro, tí kò ní ní olùgbé.”
- Jeremiah 6:9nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli ní tónítóní bí àjàrà; na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”
- Jeremiah 6:10nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́. Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn, wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.
- Jeremiah 6:11nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Èmi kún fún ìbínú Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra. “Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.
- Jeremiah 6:12nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí.
- Jeremiah 6:13nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn.
- Jeremiah 6:14nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò tó nǹkan. Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’ nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.
- Jeremiah 6:15nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú. Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,” ni Olúwa wí.