circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 4:28nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkún àwọn ọ̀run lókè yóò ṣú òòkùn nítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀ mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.”
- Jeremiah 4:29nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà gbogbo ìlú yóò sálọ. Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó; ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ. Gbogbo ìlú náà sì di ahoro; kò sì ṣí ẹnìkan nínú rẹ̀.
- Jeremiah 4:30nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán? Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ; wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ.
- Jeremiah 4:31nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí, tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọ ọmọbìnrin Sioni tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀. Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé, “Kíyèsi i mo gbé, nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”
- Jeremiah 5:1nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Lọ sókè àti sódò àwọn òpópó Jerusalẹmu, wò yíká, kí o sì mọ̀, kí o sì wá kiri. Bí o bá le è rí ẹnìkan, tí ó jẹ́ olóòtítọ́ àti olódodo, n ó dáríjì ìlú yìí.
- Jeremiah 5:2nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’ síbẹ̀ wọ́n búra èké.”
- Jeremiah 5:3nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́? Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n; ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà. Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.
- Jeremiah 5:4nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí; wọn jẹ́ aṣiwèrè, nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa, àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.
- Jeremiah 5:5nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ, n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwa àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.” Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́, wọ́n sì ti já ìdè.
- Jeremiah 5:6nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n, ìkookò aginjù yóò sì pa wọ́n run, ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, nítorí àìgbọ́ràn yín pọ, ìpadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.
- Jeremiah 5:7nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra. Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè.
- Jeremiah 5:8nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó, tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn.
- Jeremiah 5:9nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?
- Jeremiah 5:10nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run, ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá. Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.
- Jeremiah 5:11nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Ilé Israẹli àti ilé Juda ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,” ni Olúwa wí.
- Jeremiah 5:12nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa; wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan! Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá; àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.
- Jeremiah 5:13nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́, ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn. Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”
- Jeremiah 5:14nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí: “Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná, àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.
- Jeremiah 5:15nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.
- Jeremiah 5:16nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.
- Jeremiah 5:17nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ, àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ, wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ. Pẹ̀lú idà ni wọn ó run ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.
- Jeremiah 5:18nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátápátá.
- Jeremiah 5:19nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsin yìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.’
- Jeremiah 5:20nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
“Kéde èyí fún ilé Jakọbu, kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda.
- Jeremiah 5:21nǹkan bí 612 ṣáájú Kristi
Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn, tí ó lójú ti kò fi ríran tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.