circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 59:5nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀ wọn sì ń ta owú aláǹtakùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú, àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde.
- Isaiah 59:6nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán; wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn. Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn.
- Isaiah 59:7nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀; wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi; ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn.
- Isaiah 59:8nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀; kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ, kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.
- Isaiah 59:9nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa, àti tí òdodo kò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́. A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ òkùnkùn; ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.
- Isaiah 59:10nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú. Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni; láàrín alágbára àwa dàbí òkú.
- Isaiah 59:11nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Gbogbo wa là ń ké bí i beari; àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà. A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.
- Isaiah 59:12nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá. Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa, àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,
- Isaiah 59:13nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa, kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run, dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀, pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbèrò síta.
- Isaiah 59:14nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn, àti ti òdodo dúró lókèèrè; òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà, òdodo kò sì le è wọlé.
- Isaiah 59:15nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
A kò rí òtítọ́ mọ́, àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ. Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
- Isaiah 59:16nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Òun rí i pé kò sí ẹnìkan, àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́; nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀, àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.
- Isaiah 59:17nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀, àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀; ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
- Isaiah 59:18nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni yóò san án ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀; òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.
- Isaiah 59:19nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa, àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀. Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.
- Isaiah 59:20nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
“Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni, sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.
- Isaiah 59:21nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
“Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé,” ni Olúwa wí.
- Isaiah 60:1nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
“Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́.
- Isaiah 60:2nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́ ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ.
- Isaiah 60:3nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ, àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.
- Isaiah 60:4nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
“Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò. Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.
- Isaiah 60:5nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀; ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.
- Isaiah 60:6nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani. Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá, wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.
- Isaiah 60:7nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Gbogbo agbo ẹran ìlú Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ, àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́; wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi, bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.
- Isaiah 60:8nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
“Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru, gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?