Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaiah 57:15nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.

  2. Isaiah 57:16nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé, tàbí kí n máa bínú sá á, nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi èémí ènìyàn tí mo ti dá.

  3. Isaiah 57:17nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀; mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú; síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.

  4. Isaiah 57:18nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn; Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,

  5. Isaiah 57:19nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli. Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,” ni Olúwa wí, “Àti pé, Èmi yóò wo wọ́n sàn.”

  6. Isaiah 57:20nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun tí kò le è sinmi, tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.

  7. Isaiah 57:21nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    “Kò sí àlàáfíà fún àwọn ìkà,” ni Ọlọ́run mi wí.

  8. Isaiah 58:1nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    “Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn. Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè. Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn, àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  9. Isaiah 58:2nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri; wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi, àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀. Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.

  10. Isaiah 58:3nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Wọ́n wí pé, ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì rí? Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’ “Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.

  11. Isaiah 58:4nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀, àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu. Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.

  12. Isaiah 58:5nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí, ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀? Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú? Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí, ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?

  13. Isaiah 58:6nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    “Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?

  14. Isaiah 58:7nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri. Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn?

  15. Isaiah 58:8nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀ àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá; nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ, ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.

  16. Isaiah 58:9nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára, nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ,

  17. Isaiah 58:10nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan.

  18. Isaiah 58:11nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo; òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀ yóò sì fún egungun rẹ lókun. Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára, àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.

  19. Isaiah 58:12nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀.

  20. Isaiah 58:13nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    “Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi, bí ìwọ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ohun dídùn àti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀ àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí,

  21. Isaiah 58:14nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú Olúwa rẹ, èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé, àti láti máa jàdídùn ìní ti Jakọbu baba rẹ.” Ẹnu Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.

  22. Isaiah 59:1nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà, tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.

  23. Isaiah 59:2nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín; ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.

  24. Isaiah 59:3nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀, àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi. Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀, ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi.

  25. Isaiah 59:4nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo; kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́. Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́; wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà.