Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kronika 23:14nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Jehoiada àlùfáà mú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé, “Mú un jáde wá láàrín àwọn ọgbà, kí a sì fi idà pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, “Má ṣe pa á nínú ilé Olúwa.”

  2. 2 Kronika 23:15nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ipá mú un kí ó tó dé ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ẹṣin ti ilé ọba, wọ́n sì ti pa á níbẹ̀.

  3. 2 Kronika 23:16nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Jehoiada, dá májẹ̀mú pé òun àti àwọn ènìyàn àti ọba yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa.

  4. 2 Kronika 23:17nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ènìyàn lọ sí ilé Baali, wọ́n sì fà á ya lulẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti àwọn òrìṣà, wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ.

  5. 2 Kronika 23:18nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà, Jehoiada tẹ àwòrán ilé Olúwa sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ẹni tí Dafidi ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé Olúwa láti tẹ ẹbọ sísun ti Olúwa bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mose, pẹ̀lú ayọ̀ àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti pàṣẹ.

  6. 2 Kronika 23:19nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Ó mú àwọn olùṣọ́nà wà ni ipò ìdúró ní ẹnu odi ilé Olúwa kí ẹni aláìmọ́ nínú ohunkóhun kó má ba à wọlé.

  7. 2 Kronika 23:20nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Ó mú pẹ̀lú rẹ̀ àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, àwọn ẹni ọlá, àwọn olórí àwọn ènìyàn àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. Ó sì mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé Olúwa. Wọ́n lọ sínú ààfin láti ẹnu òde ti òkè. Wọ́n sì fi ọba jókòó lórí ìtẹ́.

  8. 2 Kronika 23:21nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, ìlú náà sì dákẹ́ rọ́rọ́. Nítorí a pa Ataliah pẹ̀lú idà.

  9. 2 Kronika 24:1nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Joaṣi jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibia ti Beerṣeba.

  10. 2 Kronika 24:2nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Joaṣi ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa ní gbogbo àkókò Jehoiada àlùfáà.

  11. 2 Kronika 24:3nǹkan bí 878 ṣáájú Kristi

    Jehoiada yan ìyàwó méjì fún un, ó sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.

  12. 2 Kronika 24:4nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Ní àkókò kan, Joaṣi pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe.

  13. 2 Kronika 24:5nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Ó pe àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ sì gba owó ìtọ́sí láti ọwọ́ gbogbo Israẹli láti fi tún ilé Ọlọ́run yín ṣe.” Ṣùgbọ́n àwọn ará Lefi kò ṣe é lẹ́ẹ̀kan náà.

  14. 2 Kronika 24:6nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ọba pa á láṣẹ fún Jehoiada olórí àlùfáà ó sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí o kò béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Lefi láti mú wá láti Juda àti Jerusalẹmu, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo Israẹli fún àgọ́ ẹ̀rí?”

  15. 2 Kronika 24:7nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí, àwọn ọmọkùnrin obìnrin búburú ni Ataliah ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn Baali.

  16. 2 Kronika 24:8nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Nípasẹ̀ ọba, wọn ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa.

  17. 2 Kronika 24:9nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    A ṣe ìkéde ní Juda àti Jerusalẹmu wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti béèrè lọ́wọ́ Israẹli ní aginjù.

  18. 2 Kronika 24:10nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn sì yọ̀, wọ́n sì mú un wá, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún.

  19. 2 Kronika 24:11nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Nígbàkígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará Lefi sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọba àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí ààyè rẹ̀. Wọ́n ṣe èyí déédé, wọ́n sì kó iye owó ńlá.

  20. 2 Kronika 24:12nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Ọba àti Jehoiada fi fún àwọn ọkùnrin náà tí ó sì ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Olúwa. Wọ́n fi owó gba ẹni tí ń fi òkúta mọ ilé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ilé Olúwa padà, àti àwọn òṣìṣẹ́ pẹ̀lú irin àti idẹ láti tún ilé Olúwa ṣe.

  21. 2 Kronika 24:13nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ náà, sì lọ síwájú àti síwájú ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì tún mú ilé Ọlọ́run dúró sí ipò rẹ̀, wọ́n mú un le.

  22. 2 Kronika 24:14nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì parí rẹ̀ tán, wọ́n mú owó ìyókù wá sí iwájú ọba àti Jehoiada, a sì fi ohun èlò fún ilé Olúwa, àní ohun èlò fún ìsìn àti fún ẹbọ pẹ̀lú ọpọ́n, àní ohun èlò wúrà àti fàdákà. Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé Olúwa nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ Jehoiada.

  23. 2 Kronika 24:15nǹkan bí 842 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Jehoiada di arúgbó, ó sì kún fún ọjọ́, ó sì kú, ẹni àádóje ọdún ni nígbà tí ó kú.

  24. 2 Kronika 24:16nǹkan bí 842 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní Israẹli, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀.

  25. 2 Kronika 24:17nǹkan bí 842 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ikú Jehoiada, àwọn oníṣẹ́ Juda wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn.