Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Ọba 20:19nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìjòyè kéékèèké wọ̀nyí ti àwọn ìjòyè ìgbèríko jáde ti ìlú wá, àti ogun tí ó tẹ̀lé wọn.

  2. 1 Ọba 20:20nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Olúkúlùkù sì pa ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Àwọn ará Aramu sì sá, Israẹli sì lépa wọn. Ṣùgbọ́n Beni-Hadadi ọba Aramu sì sálà lórí ẹṣin pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin.

  3. 1 Ọba 20:21nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Ọba Israẹli sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Aramu ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

  4. 1 Ọba 20:22nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Israẹli, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Aramu yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.”

  5. 1 Ọba 20:23nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìránṣẹ́ ọba Aramu sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú.

  6. 1 Ọba 20:24nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Nǹkan yìí ni kí o sì ṣe, mú àwọn ọba kúrò, olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi baálẹ̀ sí ipò wọn.

  7. 1 Ọba 20:25nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Kí o sì tún kó ogun jọ fún ara rẹ bí èyí tí ó ti sọnù; ẹṣin fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ fún kẹ̀kẹ́; kí a bá lè bá Israẹli jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítòótọ́ àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ.” Ó sì gba tiwọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

  8. 1 Ọba 20:26nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Beni-Hadadi ka iye àwọn ará Aramu, ó sì gòkè lọ sí Afeki, láti bá Israẹli jagun.

  9. 1 Ọba 20:27nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn. Àwọn ọmọ Israẹli sì dó ní òdìkejì wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Aramu kún ilẹ̀ náà.

  10. 1 Ọba 20:28nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Israẹli pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Aramu rò pé Olúwa, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”

  11. 1 Ọba 20:29nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì dó sí òdìkejì ara wọn fún ọjọ́ méje, àti ní ọjọ́ keje, wọ́n pàdé ogun. Àwọn ọmọ Israẹli sì pa ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú àwọn ará Aramu ní ọjọ́ kan.

  12. 1 Ọba 20:30nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Afeki, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàá mẹ́tàlá lé ẹgbẹ̀rún (27,000) nínú wọn. Beni-Hadadi sì sálọ sínú ìlú, ó sì fi ara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.

  13. 1 Ọba 20:31nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká. Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là.”

  14. 1 Ọba 20:32nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Israẹli wá, wọ́n sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ Beni-Hadadi wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí èmi kí ó yè.’ ” Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láààyè bí? Arákùnrin mi ni òun.”

  15. 1 Ọba 20:33nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Beni-Hadadi arákùnrin rẹ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Beni-Hadadi jáde tọ̀ ọ́ wá, Ahabu sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́.

  16. 1 Ọba 20:34nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Beni-Hadadi sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Damasku, bí baba mi ti ṣe ní Samaria.” Ahabu sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ.

  17. 1 Ọba 20:35nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, ọkùnrin kan nínú àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì wí fún èkejì rẹ̀ pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí,” ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti lù ú.

  18. 1 Ọba 20:36nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn Olúwa gbọ́, kíyèsi i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́.” Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á.

  19. 1 Ọba 20:37nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Wòlíì náà sì rí ọkùnrin mìíràn, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí.” Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà sì lù ú, ó sì pa á lára.

  20. 1 Ọba 20:38nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Wòlíì náà sì lọ, ó sì dúró de ọba ní ojú ọ̀nà. Ó pa ara rẹ̀ dà ní fífi eérú bo ojú.

  21. 1 Ọba 20:39nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Bí ọba sì ti ń rékọjá, wòlíì náà ké sí i, ó sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ jáde wọ àárín ogun lọ, ẹnìkan sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbèkùn kan, ó sì wí pé, ‘Pa ọkùnrin yìí mọ́. Bí a bá fẹ́ ẹ kù, ẹ̀mí rẹ yóò lọ dípò ẹ̀mí rẹ̀, tàbí kí ìwọ san tálẹ́ǹtì fàdákà kan.’

  22. 1 Ọba 20:40nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ìṣe níhìn-ín àti lọ́hùn ún, a fẹ́ ẹ kù.” Ọba Israẹli sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ rẹ yóò rí, ìwọ fúnra rẹ̀ ti dá a.”

  23. 1 Ọba 20:41nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni wòlíì náà yára, ó sì mú eérú kúrò ní ojú rẹ̀, ọba Israẹli sì mọ̀ ọ́n pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ni ó ń ṣe.

  24. 1 Ọba 20:42nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí fún ọba pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti jọ̀wọ́ ọkùnrin tí èmi ti yàn sí ìparun pátápátá lọ́wọ́ lọ. Nítorí náà, ẹ̀mí rẹ yóò lọ fún ẹ̀mí rẹ, ènìyàn rẹ fún ènìyàn rẹ̀.’ ”

  25. 1 Ọba 20:43nǹkan bí 901 ṣáájú Kristi

    Ọba Israẹli sì lọ sí ilé rẹ̀ ní wíwú gbọ́, inú rẹ sì bàjẹ́, ó sì wá sí Samaria.