- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Lefitiku 23:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ yìí náà ni kí ẹ kéde ìpàdé àjọ mímọ́: ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀ níbi yówù tí ẹ ń gbé.
- Lefitiku 23:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“ ‘Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
- Lefitiku 23:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 23:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Sọ fún àwọn ará Israẹli, ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, kí ẹ ní ọjọ́ ìsinmi, ìpàdé àjọ mímọ́ tí a fi fèrè fífọn ṣe ìrántí.
- Lefitiku 23:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojúmọ́, ṣùgbọ́n ẹ mú ọrẹ tí a fi iná sun wá síwájú Olúwa.’ ”
- Lefitiku 23:26nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 23:27nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa.
- Lefitiku 23:28nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú Olúwa Ọlọ́run yín.
- Lefitiku 23:29nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
- Lefitiku 23:30nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
- Lefitiku 23:31nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
- Lefitiku 23:32nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ọjọ́ ìsinmi ni fún un yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsànán oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”
- Lefitiku 23:33nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 23:34nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje.
- Lefitiku 23:35nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́.
- Lefitiku 23:36nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá, ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ pe ìpàdé mímọ́ kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa, èyí jẹ́ ìpàdé tí ó gbẹ̀yìn; ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojoojúmọ́.
- Lefitiku 23:37nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
(“ ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí Olúwa ti yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí i àjọ̀dún tí a yàn fún mímu àwọn ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa wá—ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà, ọrẹ ẹbọ àti ọrẹ ohun mímu, fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
- Lefitiku 23:38nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àwọn ọrẹ wọ̀nyí wà ní àfikún pẹ̀lú àwọn ọrẹ ọjọ́ ìsinmi Olúwa, àti pẹ̀lú ẹ̀bùn yín àti ohunkóhun tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ àti gbogbo ọrẹ àtinúwá yín fún Olúwa.)
- Lefitiku 23:39nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“ ‘Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti kórè ilẹ̀ náà, ẹ ṣe àjọ̀dún yìí fún Olúwa ní ọjọ́ méje. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú si tún jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.
- Lefitiku 23:40nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi dáradára, imọ̀ ọ̀pẹ, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, àti igi wílò odò, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.
- Lefitiku 23:41nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí Olúwa fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, ẹ ṣe é ní oṣù keje.
- Lefitiku 23:42nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ọmọ bíbí Israẹli gbé nínú àgọ́.
- Lefitiku 23:43nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí àwọn ìran yín le mọ̀ pé mo mú kí Israẹli gbé nínú àgọ́, nígbà tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
- Lefitiku 23:44nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Báyìí ni Mose kéde àwọn àjọ̀dún tí a yàn Olúwa fún àwọn ọmọ Israẹli.
- Lefitiku 24:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,