- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Lefitiku 24:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara olifi wá láti fi tan iná, kí fìtílà lè máa jò láì kú.
- Lefitiku 24:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn aṣọ ìkélé ti ibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Aaroni ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójoojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.
- Lefitiku 24:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá fìtílà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójoojúmọ́.
- Lefitiku 24:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan.
- Lefitiku 24:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fà mẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa.
- Lefitiku 24:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ sísun sí Olúwa.
- Lefitiku 24:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àkàrà yìí ni kí ẹ gbé wá síwájú Olúwa nígbàkígbà, lọ́ṣọ̀ọ̀ṣẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé.
- Lefitiku 24:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni í. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojoojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.”
- Lefitiku 24:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Ejibiti. Ó jáde lọ láàrín àwọn ọmọ Israẹli, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrín òun àti ọmọ Israẹli kan.
- Lefitiku 24:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ọmọkùnrin arábìnrin Israẹli náà sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè, wọ́n sì mú un tọ Mose wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Ṣelomiti, ọmọbìnrin Debiri, ti ẹ̀yà Dani.)
- Lefitiku 24:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Wọ́n fi í sínú túbú kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn.
- Lefitiku 24:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sì sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 24:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.
- Lefitiku 24:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
- Lefitiku 24:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọ bíbí Israẹli, bí ó bá ti sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.
- Lefitiku 24:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“ ‘Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á.
- Lefitiku 24:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.
- Lefitiku 24:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Bí ẹnìkan bá pa ẹnìkejì rẹ̀ lára, ohunkóhun tí ó ṣe ni kí ẹ ṣe sí i.
- Lefitiku 24:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yà fún ẹ̀yà, ojú fún ojú, eyín fún eyín; bí òun ti ṣe àbùkù sí ara ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni kí a ṣe sí i.
- Lefitiku 24:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó bá sì lu ẹran pa, kí ó sán an padà; ẹni tí ó bá sì lu ènìyàn pa, a ó pa á.
- Lefitiku 24:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Òfin kan náà ló wà fún àlejò àti fún ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
- Lefitiku 24:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì mú asọ̀rọ̀-òdì náà lọ sí ẹ̀yìn àgọ́, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose.
- Lefitiku 25:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose ní orí òkè Sinai pé,
- Lefitiku 25:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín, ilẹ̀ náà gbọdọ̀ sinmi fún Olúwa.
- Lefitiku 25:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi gbin oko rẹ, ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ, tí ìwọ ó sì fi kó èso wọn jọ.