Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lefitiku 22:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Aaroni bá ní ààrùn ara tí ń ran ni, tàbí ìtújáde nínú ara. Ó lè má jẹ ọrẹ mímọ́ náà títí di ìgbà tí a ó fi wẹ̀ ẹ́ mọ́. Òun tún lè di aláìmọ́ bí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí òkú nǹkan bá sọ di àìmọ́ tàbí bí ó bá farakan ẹnikẹ́ni tí ó ní ìtújáde.

  2. Lefitiku 22:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú ohun tí ń rákò, tí ó sọ ọ́ di aláìmọ́, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ ọ́ di àìmọ́, ohunkóhun yówù kí àìmọ́ náà jẹ́.

  3. Lefitiku 22:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹni náà tí ó fọwọ́ kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ọrẹ mímọ́ àyàfi bí ó bá wẹ ara rẹ̀.

  4. Lefitiku 22:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Bí oòrùn bá wọ̀, ẹni náà di mímọ́, lẹ́yìn náà ni ó tó le jẹ ọrẹ mímọ́, torí pé wọ́n jẹ́ oúnjẹ rẹ̀.

  5. Lefitiku 22:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti kú sílẹ̀, tàbí tí ẹranko fàya, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa.

  6. Lefitiku 22:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Kí àwọn àlùfáà pa ìlànà mi mọ́, kí wọn má ba à jẹ̀bi, kí wọn sì kú nítorí pé wọ́n ṣe ọrẹ wọ̀nyí pẹ̀lú fífojútẹ́ńbẹ́lú wọn. Èmi ni Olúwa tí ó sọ wọ́n di mímọ́.

  7. Lefitiku 22:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Kò sí ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ìdílé àlùfáà tí ó le jẹ ọrẹ mímọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni, àlejò àlùfáà tàbí alágbàṣe rẹ̀ kò le jẹ ẹ́.

  8. Lefitiku 22:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá ra ẹrú, pẹ̀lú owó, tàbí tí a bí ẹrú kan nínú ìdílé rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ oúnjẹ rẹ̀.

  9. Lefitiku 22:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà, kò gbọdọ̀ jẹ nínú èyíkéyìí nínú ohun ọrẹ mímọ́.

  10. Lefitiku 22:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin àlùfáà bá jẹ́ opó tàbí tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò lọ́mọ tí ó sì padà sínú ilé baba rẹ̀ láti máa gbé bẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀, ó le jẹ oúnjẹ baba rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àlejò tí kò lẹ́tọ̀ọ́ kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú oúnjẹ náà.

  11. Lefitiku 22:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì jẹ ọrẹ mímọ́ kan, ó gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe lórí ẹbọ náà fún àlùfáà, kí ó sì fi ìdámárùn-ún ohun tí ọrẹ náà jẹ́ kún un.

  12. Lefitiku 22:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá síwájú Olúwa di àìmọ́.

  13. Lefitiku 22:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn. Èmi ni Olúwa, tí ó sọ wọ́n di mímọ́.’ ”

  14. Lefitiku 22:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé,

  15. Lefitiku 22:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Sọ fún Aaroni, àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún gbogbo Israẹli kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín yálà ọmọ Israẹli ni tàbí àlejò tí ń gbé ní Israẹli bá mú ẹ̀bùn wá fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, yálà láti san ẹ̀jẹ́ tàbí ọrẹ àtinúwá.

  16. Lefitiku 22:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ gbọdọ̀ mú akọ láìní àbùkù láti ara màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́, kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.

  17. Lefitiku 22:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe mú ohunkóhun tí ó ní àbùkù wá, torí pé kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.

  18. Lefitiku 22:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Bí ẹnikẹ́ni bá mú ọrẹ àlàáfíà wá láti inú agbo màlúù tàbí ti àgùntàn, fún Olúwa láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí fún ọrẹ àtinúwá. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láìní àbùkù.

  19. Lefitiku 22:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe fi ẹranko tí ó fọ́jú, tí ó fi ara pa, tí ó yarọ, tí ó ní kókó, tí ó ní èkúkú, èépá àti egbò kíkẹ̀ rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé èyíkéyìí nínú wọn sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bi ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.

  20. Lefitiku 22:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ le mú màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù tàbí tí ó yọ iké wá fún ọrẹ àtinúwá, ṣùgbọ́n kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ ẹ̀jẹ́.

  21. Lefitiku 22:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe fi ẹranko tí kóró ẹpọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí a tẹ̀, tàbí tí a yà tàbí tí a là rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí ní ilẹ̀ yín.

  22. Lefitiku 22:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín. A kò nígbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù, wọ́n sì díbàjẹ́.’ ”

  23. Lefitiku 22:26nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé,

  24. Lefitiku 22:27nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Láti ọjọ́ kẹjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí Olúwa.

  25. Lefitiku 22:28nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe pa màlúù àti ọmọ rẹ̀ tàbí àgùntàn àti ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.