Fò sí àkóónú

circa 1406–1380 BC

Conquest of Canaan

Joshua leads Israel across the Jordan into the promised land, defeating the Canaanite kingdoms one by one.

658 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Joṣua 24:1nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Joṣua pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli jọ ní Ṣekemu. Ó pe àwọn àgbàgbà, àwọn olórí, onídàájọ́ àti àwọn ìjòyè Israẹli, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.

  2. Joṣua 24:2nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Joṣua sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wí, ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Tẹra baba Abrahamu àti Nahori ń gbé ní ìkọjá odò Eufurate, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà.

  3. Joṣua 24:3nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n mo mú Abrahamu baba yín kúrò ní ìkọjá odò Eufurate, mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kenaani, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Isaaki,

  4. Joṣua 24:4nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    àti fún Isaaki ni mo fún ní Jakọbu àti Esau, mo sì fún Esau ní ilẹ̀ orí òkè Seiri ní ìní, ṣùgbọ́n Jakọbu àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.

  5. Joṣua 24:5nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mose àti Aaroni, mo sì yọ Ejibiti lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.

  6. Joṣua 24:6nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Ejibiti, ẹ wá sí Òkun, àwọn ará Ejibiti lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun Pupa.

  7. Joṣua 24:7nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárín yín àti àwọn ará Ejibiti, ó sì mú òkun wá sí orí wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ejibiti. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní aginjù fún ọjọ́ pípẹ́.

  8. Joṣua 24:8nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    “ ‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jordani. Wọ́n bá yín jà, ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò níwájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn.

  9. Joṣua 24:9nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, múra láti bá Israẹli jà, ó ránṣẹ́ sí Balaamu ọmọ Beori láti fi yín bú.

  10. Joṣua 24:10nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Balaamu, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín síwájú àti síwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

  11. Joṣua 24:11nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ rékọjá Jordani, tí ẹ sì wá sí Jeriko. Àwọn ará ìlú Jeriko sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Amori, Peresi, Kenaani, Hiti, Girgaṣi, Hifi àti Jebusi. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

  12. Joṣua 24:12nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọba Amori méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín.

  13. Joṣua 24:13nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́; ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà olifi tí ẹ kò gbìn.’

  14. Joṣua 24:14nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate àti ní Ejibiti kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa.

  15. Joṣua 24:15nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa, nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate, tàbí òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn.”

  16. Joṣua 24:16nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ Olúwa sílẹ̀ láti sin òrìṣà!

  17. Joṣua 24:17nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Ejibiti, ní oko ẹrú. Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí a là kọjá.

  18. Joṣua 24:18nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè jáde kúrò ní iwájú wa, pẹ̀lú àwọn Amori, tí ń gbé ilẹ̀ náà. Àwa náà yóò máa sin Olúwa, nítorí òun ni Ọlọ́run wa.”

  19. Joṣua 24:19nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Joṣua sì wí fún àwọn ènìyàn náà, pé, “Ẹ̀yin kò le sin Olúwa, nítorí Ọlọ́run mímọ́ ni òun; Ọlọ́run owú ni òun, kì yóò dárí ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

  20. Joṣua 24:20nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan.”

  21. Joṣua 24:21nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Joṣua pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa.”

  22. Joṣua 24:22nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà ni Joṣua wí pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín pé, ẹ ti yàn láti sin Olúwa.” Wọ́n dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí.”

  23. Joṣua 24:23nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Joṣua dáhùn wí pé, “Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárín yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.”

  24. Joṣua 24:24nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn náà sì wí fún Joṣua pé, “Olúwa Ọlọ́run nìkan ni àwa yóò máa sìn, òun nìkan ni àwa yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí.”

  25. Joṣua 24:25nǹkan bí 1427 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà Joṣua dá májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Ṣekemu.