Skip to content

Jericho

58 verses

31.8700, 35.4400 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jericho

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí Jeriko àti Ai,

  2. Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn.

  3. Ní ọjọ́ náà Joṣua gba Makkeda. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátápátá, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Makkeda gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jeriko.

  4. Olúwa sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Joṣua fi idà pa. Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀: Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jeriko.

  5. Ọba Jeriko, ọ̀kan ọba Ai (tí ó wà nítòsí Beteli), ọ̀kan

  6. Èyí ni ogún tí Mose fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà kejì Jordani ní ìlà-oòrùn Jeriko.

  7. Ìpín ti àwọn ọmọ Josẹfu láti Jordani lẹ́bàá Jeriko, ní omi Jeriko ní ìhà ìlà-oòrùn, àní aginjù, tí ó gòkè láti Jeriko lọ dé ilẹ̀ òkè Beteli.

  8. Láti Janoa ó yípo lọ sí gúúsù sí Atarotu àti Naara, ó sì dé Jeriko, ó sì pín sí odò Jordani.

  9. Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jordani, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jeriko ní ìhà àríwá, ó sì forí lé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí aginjù Beti-Afeni.

  10. Ẹ̀yà Benjamini ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí: Jeriko, Beti-Hogla, Emeki-Keṣiṣi,

  11. Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani ti Jeriko, wọ́n ya Beseri ní aginjù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀yà Reubeni, Ramoti ní Gileadi ní ẹ̀yà Gadi, àti Golani ní Baṣani ní ẹ̀yà Manase.

  12. “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ rékọjá Jordani, tí ẹ sì wá sí Jeriko. Àwọn ará ìlú Jeriko sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Amori, Peresi, Kenaani, Hiti, Girgaṣi, Hifi àti Jebusi. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

  13. Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”

  14. Ní ìgbà ayé Ahabu, Hieli ará Beteli kọ́ Jeriko. Ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀ ní Abiramu, àkọ́bí rẹ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ kọ́ ní Segubu àbíkẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Joṣua ọmọ Nuni sọ.

  15. Nígbà náà Elijah sì wí fún un pé, “Dúró níbí, Eliṣa: Olúwa ti rán mi lọ sí Jeriko.” Ó sì dá a lóhùn pé, “Bí ó ti dájú pé Olúwa yè àti tí ìwọ náà yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Wọ́n sì jọ lọ sí Jeriko.

  16. Àwọn ọmọ wòlíì tí ó wà ní Jeriko sì gòkè tọ Eliṣa wá wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ wí pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?” “Bẹ́ẹ̀ ni, èmi mọ̀,” Ó dá wọn lóhùn, “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀.”

  17. Àwọn ọmọ wòlíì láti Jeriko, tí wọ́n ń wò, wí pé, “Ẹ̀mí Elijah sinmi lé Eliṣa.” Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀.

  18. Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, tí ó dúró ní Jeriko, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”

  19. Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká,

  20. Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa,

  21. Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dafidi nípa àwọn ọkùnrin rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi. Ọba wí pe, “Dúró ní Jeriko títí tí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ẹ padà wá”.

  22. Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lú orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbèkùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jeriko, ìlú ọ̀pẹ, wọ́n sì padà sí Samaria.

  23. Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún (345)

  24. Àwọn ọkùnrin Jeriko sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sakkuri ọmọ Imri sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ọkùnrin Jeriko.

  25. Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún (345).