Fò sí àkóónú

Isaac

123 ẹsẹ · 12 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Isaac

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.” Nítorí ìdí èyí, Mose sì pa ojú rẹ̀ mọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti bojú wo Ọlọ́run.

  2. Ọlọ́run sì wí fún Mose pẹ̀lú pé, “Báyìí ni kí ìwọ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu; ni ó rán mi sí i yín.’ “Èyí ni orúkọ mi títí ayérayé, orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí mi láti ìran dé ìran.

  3. “Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé, lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti.

  4. Olúwa sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu; tí farahàn ọ́.”

  5. Mo fi ara hàn Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu bí Ọlọ́run alágbára, ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi Olúwa, Èmi kò fi ara mi hàn wọ́n.

  6. Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Abrahamu. Isaaki àti Jakọbu. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, Èmi ni Olúwa.’ ”

  7. Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnra rẹ̀, ‘Tí o wí fún wọn pé, Èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ”

  8. Olúwa sọ fún Mose pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Ejibiti wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ti pinnu ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’

  9. Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jakọbu àti pẹ̀lú Isaaki àti pẹ̀lú Abrahamu, Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà.

  10. ‘Nítorí wọn kò tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó gòkè láti Ejibiti ni yóò rí ilẹ̀ tí mo pinnu gẹ́gẹ́ bí ìbúra fún Abrahamu, fún Isaaki àti fún Jakọbu:

  11. Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín, ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí Olúwa ti búra wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”

  12. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú yín dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín, fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu láti fi fún un yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńlá ńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ,

  13. Kì í ṣe nítorí òdodo yín, tàbí ìdúró ṣinṣin ni ẹ ó fi wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.

  14. Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu. Fojú fo orí kunkun àwọn ènìyàn yìí, pẹ̀lú ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  15. láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.

  16. kí ìwọ kí ó le máa fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, fetísílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí Olúwa ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.

  17. Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò dé bẹ̀.”

  18. Ṣùgbọ́n mo mú Abrahamu baba yín kúrò ní ìkọjá odò Eufurate, mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kenaani, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Isaaki,

  19. àti fún Isaaki ni mo fún ní Jakọbu àti Esau, mo sì fún Esau ní ilẹ̀ orí òkè Seiri ní ìní, ṣùgbọ́n Jakọbu àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.

  20. Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣálẹ́, wòlíì Elijah sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Israẹli àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ.

  21. Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.

  22. Àwọn ọmọ Abrahamu: Isaaki àti Iṣmaeli.

  23. Abrahamu sì jẹ́ baba Isaaki. Àwọn ọmọ Isaaki: Esau àti Israẹli.

  24. májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.

  25. Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wa Abrahamu, Isaaki àti Israẹli pa ìfẹ́ yìí mọ́ nínú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtítọ́ sí ọ.