Fò sí àkóónú

Isaac

123 ẹsẹ · 12 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Isaac

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ́ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Israẹli àti Juda; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki, àti Israẹli, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria.

  2. májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.

  3. Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọ lẹ́yìn Jakọbu àti Dafidi ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákòóso lórí àwọn ọmọ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu; nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà; èmi ó sì ṣàánú fún wọn.’ ”

  4. “Ibi gíga Isaaki wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoro àti ibi mímọ Israẹli wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro. Èmi yóò sì fi idà dìde sí ilé Jeroboamu.”

  5. Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé, “ ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli, má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’

  6. Abrahamu ni baba Isaaki; Isaaki ni baba Jakọbu; Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

  7. Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run.

  8. ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”

  9. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’

  10. Tí í ṣe ọmọ Jakọbu, tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu, tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,

  11. “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.

  12. Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’

  13. Ọlọ́run Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, Ọlọ́run àwọn baba wa, òun ni ó ti yin Jesu ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo; ẹni tí ẹ̀yin ti fi lé wọn lọ́wọ́, tí ẹ̀yin sì sẹ́ níwájú Pilatu, nígbà tí ó ti pinnu rẹ̀ láti dá a sílẹ̀.

  14. Ó sì fún Abrahamu ni májẹ̀mú ìkọlà. Abrahamu bí Isaaki, ó kọ ọ́ ní ilà ni ọjọ́ kẹjọ tí ó bí i. Isaaki sí bí Jakọbu, Jakọbu sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.

  15. wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu,’ Mose sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dáṣà láti wò ó mọ́.

  16. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ. Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.”

  17. Kì í sì í ṣe kìkì èyí, ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa.

  18. Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki.

  19. Nípa ìgbàgbọ́ ní o ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí, bí ẹni pé ni ilẹ̀ àjèjì, o ń gbé inú àgọ́, pẹ̀lú Isaaki àti Jakọbu, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀,

  20. Nípa ìgbàgbọ́ ni Abrahamu, nígbà tí a dán an wò láti, fi Isaaki rú ẹbọ: àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kan ṣoṣo rú ẹbọ.

  21. Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.”

  22. Nípa ìgbàgbọ́ ní Isaaki súre fún Jakọbu àti Esau ní ti ohun tí ń bọ̀.

  23. Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Abrahamu baba wa láre, nígbà tí ó fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ lórí pẹpẹ?