God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Èmi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbẹ̀rù àti ìfòyà yín sára gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run láti òní lọ. Wọn yóò gbọ́ ìròyìn in yín, wọn yóò sì wárìrì, wọn yóò sì wà nínú ìdààmú ọkàn torí i tiyín.”
gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Esau tí ó ń gbé ní Seiri àti àwọn ará Moabu tí ó ń gbé ní Ari, ti gbà wá láààyè títí a fi la Jordani já dé ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò fún wa.”
Ṣùgbọ́n Sihoni ọba Heṣboni kò gbà fún wa láti kọjá. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti mú ọkàn rẹ̀ yigbì, àyà rẹ̀ sì kún fún agídí kí ó ba à le fi lé e yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe báyìí.
Olúwa sì bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kíyèsi i, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Sihoni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé e yín lọ́wọ́. Báyìí, ẹ máa ṣẹ́gun rẹ̀, kí ẹ sì gba ilẹ̀ rẹ̀.”
Olúwa Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ológun rẹ̀.
Láti Aroeri, létí odò Arnoni àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, Olúwa Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa.
Ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa Ọlọ́run wa, ẹ kò súnmọ́ ọ̀kan nínú ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dé ilẹ̀ tí ó lọ sí Jabbok, tàbí ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú òkè e nì ká.
Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. Kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wa fi Ogu ọba Baṣani àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. A kọlù wọ́n títí kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè.
Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, “Olúwa Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ní i. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín: ará Israẹli.
títí di ìgbà tí Olúwa yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jordani. Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un.”
Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún Joṣua pé, “Ìwọ tí fi ojú rẹ rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò ṣe sí àwọn ilẹ̀ ọba tí ẹ̀yin n lọ.
Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, Olúwa Ọlọ́run yín tìkára rẹ̀ ni yóò jà fún un yín.”
Nígbà náà ni mo bẹ Olúwa wí pé,
“Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí bẹ̀rẹ̀ sí fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ. Ọlọ́run wo ló tó bẹ́ẹ̀ láyé àti lọ́run tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tí o ti ṣe?
Jẹ́ kí n kọjá lọ wo ilẹ̀ rere ti ìkọjá Jordani, ilẹ̀ òkè dídára nì àti Lebanoni.”
Ṣùgbọ́n torí i tiyín, Olúwa Ọlọ́run bínú sí mi kò sì gbọ́ tèmi. Olúwa sọ wí pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ yìí sí mi mọ́.
Gbọ́ Israẹli, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín. Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín.
Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, ṣùgbọ́n ẹ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.
Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Olúwa ṣe ní Baali-Peori. Olúwa Ọlọ́run yín run gbogbo àwọn tí ó tẹ̀lé òrìṣà Baali-Peori kúrò ní àárín yín.
Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láààyè lónìí.
Ẹ kíyèsi i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí Olúwa Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní.
Orílẹ̀-èdè olókìkí wo ni ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkígbà tí a bá ń ké pè é?
Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”
Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárín iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́.