Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò rán iná sí ara odi Rabba èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun, pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà.

  2. Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn, òun àti àwọn ọmọ-aládé rẹ̀ lápapọ̀,” ni Olúwa wí.

  3. Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, nítorí ó ti sun ún, di eérú, egungun ọba Edomu,

  4. Èmi yóò rán iná sí orí Moabu èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run. Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè.

  5. Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,” ni Olúwa wí.

  6. Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́. Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà, òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé,

  7. Èmi yóò rán iná sí orí Juda èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.”

  8. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.

  9. Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀, bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára. Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà, láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.

  10. “Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari. Òun sì le koko bí igi óákù mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá.

  11. Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.

  12. “Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?” ni Olúwa wí.

  13. “Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀ bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.

  14. Àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ yóò sálọ ní ìhòhò ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí.

  15. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Ejibiti:

  16. “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí; nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”

  17. Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú, àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù? Tí ewu bá wa lórí ìlú kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á?

  18. Nítòótọ́ Olúwa Olódùmarè kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.

  19. Kìnnìún ti bú ramúramù ta ni kì yóò bẹ̀rù? Olúwa Olódùmarè ti sọ̀rọ̀ ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀?

  20. “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí, “àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”

  21. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”

  22. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”

  23. “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.

  24. “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀.

  25. Èmi yóò wó ilé òtútù lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru; ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé a ó sì pa ilé ńlá náà run,” ni Olúwa wí.