God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,” ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.
Olúwa Olódùmarè ti búra fúnra rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé: “Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀, Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”
Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”
Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà, Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú, àti àwọn ilé kéékèèké sí wẹ́wẹ́.
Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Israẹli, wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà, láti Lebo-Hamati, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah.”
Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Ó pèsè ọwọ́ eṣú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀.
Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí. “Èyí kò ni ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa wí.
Èyí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Olúwa Olódùmarè ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run.
Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí. “Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
Èyí ni ohun tí ó fihàn mí: Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀.
Olúwa sì bi mi pé, “Amosi, kí ni ìwọ rí?” Mo dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n.” Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Wò ó, Èmí ń gbé okùn ìwọ̀n kalẹ̀ láàrín àwọn Israẹli ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́.
“Ibi gíga Isaaki wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoro àti ibi mímọ Israẹli wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro. Èmi yóò sì fi idà dìde sí ilé Jeroboamu.”
Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’
Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé, “ ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli, má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’
“Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí: “ ‘Ìyàwó rẹ yóò di panṣágà ni ìlú, àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú. A ó fi okùn wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín in àti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́. Israẹli yóò sì lọ sí ìgbèkùn, kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”
Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n.
Ó béèrè pé, “Amosi kí ni ìwọ rí.” Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.” Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Israẹli; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”
Olúwa Olódùmarè wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹmpili yóò yí padà sí ohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”
Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé, “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe.
“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán, Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.
Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀, gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún. Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí a sì fá orí yín. Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí àti òpin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò.
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti Òkun dé Òkun wọn yóò sì máa rìn ká láti gúúsù sí àríwá, wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.