God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, èyí tí àwa ń rán ọ sí, kí ó ba à lè dára fún wa. Nítorí pé àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá,
Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: ‘Èyí ni ẹni tí ẹ̀yin ti rán láti gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ síwájú mi.
Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkàn padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín.
Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọba Babeli tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbà yín ní ọwọ́ rẹ̀.
Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’
“Ṣùgbọ́n sá, bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa kò ní gbé ilẹ̀ yìí,’ ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín.
nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Juda èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Ejibiti láti lọ ṣe àtìpó níbẹ̀.
Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Ejibiti ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’
Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà síta sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Ejibiti. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹni ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’
“Ẹ̀yin yòókù Juda, Olúwa ti sọ fún un yín pé, ‘Kí ẹ má ṣe lọ sí Ejibiti.’ Ẹ mọ èyí dájú, èmi kìlọ̀ fún un yín lónìí,
pé àṣìṣe ńlá gbá à ni ẹ̀yin ṣe nígbà tí ẹ̀yin rán mi sí Olúwa Ọlọ́run yín pé, ‘Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa; sọ fún wa gbogbo ohun tí ó bá sọ, àwa yóò sì ṣe é.’
Mo ti sọ fún un yín lónìí, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹ̀yin kò tí ì gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run yín, àti gbogbo ohun tí ó rán mi láti sọ fún un yín.
Nígbà tí Jeremiah parí sísọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rán an sí wọn tan.
Asariah ọmọ Hoṣaiah àti Johanani ọmọ Karea, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremiah pé, “Ìwọ ń pa irọ́! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Ejibiti láti ṣàtìpó níbẹ̀.’
Nítorí náà, Johanani ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Juda.
Nítorí náà, wọn wọ Ejibiti pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Tafanesi.
Ní Tafanesi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá:
Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí. Èmi yóò ránṣẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli, Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ.
“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Wo ibi tí mo mú bá Jerusalẹmu àti gbogbo ìlú Juda. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun.
Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun ìríra yìí tí èmi kórìíra.’
Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Juda àti òpópó Jerusalẹmu àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.
“Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí, kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Juda ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan?
Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo.