Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.”

  2. Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Igdaliah, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Maaseiah, ọmọ Ṣallumu olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà.

  3. Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé:

  4. “Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.

  5. ‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.

  6. Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.

  7. Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jehonadabu ọmọ Rekabu pa òfin baba wọn mọ́ tí ó pàṣẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’

  8. “Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Juda, àti sórí gbogbo olùgbé Jerusalẹmu nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”

  9. Nígbà náà ni Jeremiah wí fún ìdílé Rekabu pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jehonadabu baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó pàṣẹ fún un yín.’

  10. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Jonadabu ọmọ Rekabu kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí.’ ”

  11. Ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé:

  12. “Mú ìwé kíká fún ará rẹ, kí o sì kọ sínú rẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ nípa Israẹli àti ti Juda, àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè láti ìgbà tí mo ti sọ fún ọ láti ọjọ́ Josiah títí di òní.

  13. Ó lè jẹ́ wí pé ilé Juda yóò gbọ́ gbogbo ibi tí mo ti pinnu láti ṣe fún wọn; kí wọn kí ó sì yípadà, olúkúlùkù wọn kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀. Kí èmi kí ó lè dárí àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.”

  14. Nígbà náà ni Jeremiah pe Baruku ọmọ Neriah, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá a sọ fún, Baruku sì kọ láti ẹnu Jeremiah, gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ fún un sórí ìwé kíká náà.

  15. Nígbà náà ni Jeremiah wí fún Baruku pé, “A sé mi mọ́! Èmi kò lè lọ sí ilé Olúwa.

  16. Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé Olúwa ní ọjọ́ àwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíká náà ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ ti ẹnu mi kọ; ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Juda, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn.

  17. Ó lè jẹ́ pé, ẹ̀bẹ̀ wọn yóò wá sí iwájú Olúwa, wọ́n ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn; nítorí pé títóbi ni ìbínú àti ìrunú tí Olúwa ti sọ sí àwọn ènìyàn yìí.”

  18. Baruku ọmọ Neriah sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremiah sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa.

  19. Ní oṣù kẹsànán ọdún karùn-ún Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda ni wọ́n kéde àwẹ̀ níwájú Olúwa fún gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti ìlú Juda.

  20. Láti inú yàrá Gemariah ọmọ Ṣafani akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tuntun. Baruku sì ka ọ̀rọ̀ Jeremiah láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn.

  21. Nígbà tí Mikaiah ọmọ Gemariah ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé náà;

  22. Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Olúwa fi wọ́n pamọ́.

  23. Lẹ́yìn tí ọba fi ìwé kíká náà tí ọ̀rọ̀ tí Baruku kọ láti ẹnu Jeremiah jóná tán, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá:

  24. Kí o sì wí fún Jehoiakimu ọba Juda pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lóòtítọ́ ni ọba Babeli yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.”

  25. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí ní ti Jehoiakimu ọba Juda pé, Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru.