Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa sì farahàn Solomoni ní òru ó sì wí pé: “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibí yìí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ.

  2. “Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma bá à sí òjò, tàbí láti pàṣẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín àwọn ènìyàn mi,

  3. tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn.

  4. Nísinsin yìí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbí yìí.

  5. Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé.

  6. “Ní ti bí ìwọ bá rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ, tí ìwọ sì ṣe àkíyèsí àṣẹ mi láti ọ̀run,

  7. Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe pẹ̀lú Dafidi baba rẹ nígbà tí mo bá a dá májẹ̀mú wí pé, ìwọ kò ní fẹ́ ẹnìkan kù láti ṣe alákòóso lórí Israẹli.

  8. “Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá yípadà tí o sì kọ òfin mi sílẹ̀ àti àṣẹ tí mo ti fi fún yín tí ẹ sì lọ sókè láti lọ sin ọlọ́run mìíràn tí ẹ sì bọ wọ́n,

  9. nígbà náà ni èmi yóò fa Israẹli tu kúrò láti ilẹ̀ mi, èyí tí èmi ti fi fún wọn, èmi yóò sì kọ̀ ilé náà sílẹ̀ èyí tí èmi ti yà sọ́tọ̀ fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ṣe ọ̀rọ̀ òwe, n ó fi ṣe ẹlẹ́yà láàrín gbogbo ènìyàn,

  10. àti ní gbogbo àyíká ilé yìí nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni yóò di ohun ìtànjẹ; gbogbo àwọn tí ó bá sì kọjá níbẹ̀ ni yóò jáláyà, wọn yóò sì wí pé, ‘Kí ni ó dé tí Olúwa fì ṣe irú èyí sí ilẹ̀ yí àti sí ilé yìí?’

  11. Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run baba wọn ẹni tí ó mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti fi ọwọ́ gba ọlọ́run mìíràn mọ́ra, wọ́n bọ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyí tí ó fi mú gbogbo ìjàǹbá náà wá sórí wọn.’ ”

  12. Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Solomoni kọ́ ilé Olúwa àti ilé òun fúnra rẹ̀.

  13. Solomoni gbé ọmọbìnrin Farao sókè láti ìlú Dafidi lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé, “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dafidi ọba Israẹli nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí Olúwa bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”

  14. Lórí pẹpẹ Olúwa tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Solomoni sì rú ẹbọ sísun sí Olúwa,

  15. Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dafidi, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojoojúmọ́. Ó sì tún yàn àwọn olùṣọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà, nítorí èyí ni Dafidi ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ.

  16. Gbogbo iṣẹ́ Solomoni ni a gbé jáde láti ọjọ́ ìfi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ ìparí. Bẹ́ẹ̀ ni ilé Olúwa sì parí.

  17. oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa, ó sì dá a lágara fún ìyàlẹ́nu.

  18. Ìyìn ló yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.”

  19. Ọba sì lo igi algumu náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Kò sì ṣí irú rẹ̀ tí a ti rí rí ní ilẹ̀ Juda.

  20. Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojúrere lọ́dọ̀ Solomoni láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀.

  21. Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fetísí àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati nípasẹ̀ Ahijah ará Ṣilo.

  22. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé,

  23. ‘Èyí ní ohun tí Olúwa wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ láti lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jeroboamu.

  24. Àwọn ará Lefi fi ìgbèríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Juda àti Jerusalẹmu nítorí Jeroboamu àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa.

  25. Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tẹ̀lé àwọn ará Lefi lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run baba a wọn.