God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
“Nígbà tí a bá ti ọ̀run, tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú,
nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó máa rìn, kí o sì rọ òjò sórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní.
Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Israẹli olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé Olúwa yìí.
Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run ibùgbé rẹ dáríjì, kí o sì pín fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí i gbogbo ohun tí ó ṣe, nígbà tí ìwọ ti mọ ọkàn rẹ̀ (nítorí ìwọ nìkan ni ó mọ ọkàn ènìyàn.)
Bẹ́ẹ̀ ni kí wọn kí ó lè bẹ̀rù rẹ kí wọn kí ó sì rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń gbé nínú ilé tí o ti fi fún àwọn baba wa.
“Ní ti àwọn àlejò tí wọn kò sí lára àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ṣùgbọ́n tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn nítorí orúkọ ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá wá tí ó sì gbàdúrà pẹ̀lú kíkojú si ilé Olúwa yìí.
Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run àní láti ibi ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe ohun tí àwọn àlejò béèrè lọ́wọ́ rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ènìyàn ayé kí wọn lè mọ orúkọ rẹ kí wọn sì bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì lè mọ̀ wí pé ilé yìí tí èmi ti kọ, orúkọ rẹ ni ó ń jẹ́.
“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀tá wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ si ìhà ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé Olúwa tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ.
Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.
“Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí,
ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’;
tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, kojú si ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé Olúwa tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ;
nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọn, tí wọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.
“Nísinsin yìí, Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ojú rẹ kí ó ṣí kí o sì tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ fún àdúrà sí ibí yìí.
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìde, Olúwa Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ,
Olúwa Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni àmì òróró rẹ.
Nígbà tí Solomoni sì ti parí àdúrà, iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó ẹbọ sísun àti ẹbọ, ògo Ọlọ́run sì kún ilé Olúwa.
Àwọn àlùfáà kò sì le wo ilé Olúwa náà nítorí pé ògo Olúwa kún un.
Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo Olúwa lórí ilé Olúwa náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú ni dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin Olúwa, wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa wí pé, “Nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.”
Nígbà náà ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn sì rú ẹbọ níwájú Olúwa.
Ọba Solomoni sì rú ẹbọ ti ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000), orí màlúù àti àgùntàn àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn àti ẹranko. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn ya ilé Ọlọ́run sí mímọ́.
Àwọn àlùfáà dúró ní ààyè wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ti ṣe pẹ̀lú ohun èlò orin Olúwa, tí ọba Dafidi ti ṣe fún ìyìn Olúwa àti tí á lò nígbà tí ó dúpẹ́, wí pé, “Àánú rẹ̀ sì dúró láéláé,” níwájú àwọn ọmọ Lefi, àwọn àlùfáà sì fọn ìpè, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dúró.
Solomoni sì yà àgbàlá níwájú ilé Olúwa sọ́tọ̀, níbẹ̀ sì ni ó ti ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ó ti ṣe kò lè gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọ̀rá náà.
Ní ọjọ́ kẹtàlélógún tí oṣù keje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dafidi àti Solomoni, àti fún àwọn ènìyàn Israẹli.
Nígbà tí Solomoni ti parí ilé Olúwa àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé Olúwa àti nínú ilé òun tìkára rẹ̀,