Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Years

27 ẹsẹ · 19 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún.

  2. Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún, ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti.

  3. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta (600) ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀.

  4. Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́.

  5. Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yìn àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà.

  6. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ.

  7. “Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà, ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè ìgbà òtútù àti ìgbà ooru, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò, ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru, yóò wà títí láé.”

  8. Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Abrahamu lò láyé jẹ́ igba kan ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175).

  9. Abrahamu sì kú ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó dàgbà, ó darúgbó kí ó tó kú. A sì sin ín sí ibojì àwọn ènìyàn rẹ̀.

  10. “Oṣù yìí ni yóò jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ fún yín, oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún yín.

  11. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi: ìsinmi fún Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ.

  12. Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnra rẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá.

  13. Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣooṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin.

  14. àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn.

  15. Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi, pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.

  16. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san Olúwa ni, àti ọdún ìsanpadà, nítorí ọ̀ràn Sioni.

  17. láti kéde ọdún ojúrere Olúwa àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

  18. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé.

  19. Kò ní ṣẹ́kù ohunkóhun sílẹ̀ fún wọn nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí àwọn ènìyàn Anatoti ní ọdún ìbẹ̀wò wọn.’ ”

  20. “Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn; níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú. Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,” ni Olúwa wí.

  21. Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mú kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ní àárín ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Àti lórí apá kan ni yóò dà ìríra tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a.”

  22. “Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290).

  23. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì (1,335) ọjọ́.

  24. Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Elisabeti yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.

  25. láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.”