Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sheep

144 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé ìlú Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ; ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ.

  2. Ìwọ jẹ wàrà. O sì wọ aṣọ olówùú sí ara rẹ, o sì ń pa ẹran tí ó wù ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò tọ́jú agbo ẹran.

  3. Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn.

  4. Èmi yóò mú wọn jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì kó wọn jọ láti inú àwọn ìlú, èmi yóò sì mú wọn wá sí ilẹ̀ ara wọn. Èmi yóò mú wọn jẹ ni orí àwọn òkè gíga Israẹli, ni àárín àwọn òkè àti ní gbogbo ibùdó ilẹ̀ náà.

  5. Èmi yóò ṣe àwárí àwọn tí ó nú, èmi yóò mú àwọn tí ó ń rin ìrìn àrè kiri padà. Èmi yóò di ọgbẹ́ àwọn tí ó fi ara pa, èmi yóò sì fún àwọn aláìlágbára ni okun, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra tí ó sì ni agbára ní èmi yóò parun. Èmi yóò ṣe olùṣọ́ àwọn agbo ẹran náà pẹ̀lú òdodo.

  6. “Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Israẹli, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí àgùntàn,

  7. “Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jakọbu; Èmi yóò gbá ìyókù Israẹli jọ. Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn, ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.

  8. Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín àwọn aláìkọlà ní àárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí i kìnnìún láàrín àwọn ẹranko inú igbó, bí i ọmọ kìnnìún láàrín agbo àgùntàn, èyí tí ó máa ń fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, tí kò sì ṣí ẹnìkan tí ó lè gbà á là.

  9. “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n.

  10. Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Israẹli tí ó nù lọ.

  11. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kójọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́.

  12. Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì.

  13. Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀.

  14. Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòtítọ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.

  15. “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, òun náà ni olè àti ọlọ́ṣà.

  16. Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò síwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀.

  17. Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.”

  18. Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn.

  19. Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi, ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn.

  20. Èmi ni ìlẹ̀kùn, bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko.

  21. Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun; èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  22. “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.

  23. Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri.

  24. Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.

  25. “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí.