Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sheep: Jacob's management of

9 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Jacob's management of

  1. Jẹ́ kí èmi kí ó la agbo ẹran kọjá ní òní, èmi yóò sì mú gbogbo àgùntàn onílà àti èyí tí ó ní àmì, àti gbogbo àgbò dúdú pẹ̀lú ewúrẹ́ onílà tàbí tí ó ní àmì. Àwọn wọ̀nyí ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ mi.

  2. Òtítọ́ inú mi yóò sì jẹ́rìí fún mi ní ọjọ́ iwájú nígbà tí ìwọ bá wo owó iṣẹ́ mi tí ìwọ san fún mi, yóò sì ṣe pé gbogbo èyí tí kì í bá ṣe onílà tàbí alámì nínú ewúrẹ́ tàbí tí kì í ṣe dúdú nínú àgùntàn, tí o bá rí ni ọ̀dọ̀ mi ni kí o kà sí mi lọ́rùn pé jíjí ni mo jí gbé.”

  3. Labani sì dáhùn pé, “Mo fi ara mọ́ ọn, ṣe bí ìwọ ti wí.”

  4. Ní ọjọ́ náà gan an ni Labani kó gbogbo ewúrẹ́ tí ó ní àmì tàbí ilà (àti òbúkọ àti abo, tí ó ní funfun díẹ̀ lára), pẹ̀lú gbogbo àgùntàn dúdú, ó sì fi wọ́n sí ìtọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

  5. Ibi tí Labani àti Jakọbu sì wà sí ara wọn, sì tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Jakọbu sì ń tọ́jú agbo ẹran Labani tí ó kù.

  6. Nígbà náà ni Jakọbu gé ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ tútù kan lára igi Poplari, àti igi almondi àti igi Pileeni. Ó sì bó èèpo kúrò ní ibi kọ̀ọ̀kan lára igi náà láti fún igi náà ní àwọ̀ ju ẹyọ kan lọ.

  7. Ó sì mú àwọn ọ̀pá wọ̀nyí tì sí ọ̀ọ́kán agbada omi níbi tí àwọn ẹran ti lè rí i nígbà tí wọ́n bá wá mu omi.

  8. Tí àwọn ẹran bá sì ń gùn, níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọn sì bí àwọn ẹran onílà àti alámì, àwọn tí ó ní tótòtó lára.

  9. Nígbà náà ni ó ya àwọn abo ẹran kúrò nínú agbo ẹran Labani, ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àgbò, ó sì mú kí wọn máa gùn pẹ̀lú àwọn àgbò Jakọbu dúdú nìkan, bẹ́ẹ̀ ni ó kó agbo ẹran jọ fún ara rẹ̀ láti ara agbo ẹran Labani.