Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sheep: Flesh of, extensively used as food

5 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Flesh of, extensively used as food

  1. Abigaili sì yára, ó sì mú igbá ìṣù àkàrà àti ìgò ọtí wáìnì méjì, àti àgùntàn márùn-ún, tí a ti ṣè, àti òsùwọ̀n àgbàdo yíyan márùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún ìdì àjàrà, àti igba àkàrà èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì dìwọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

  2. Òun sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ màlúù, àti ẹran tí ó ní ọ̀rá, àti àgùntàn rú ẹbọ, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, àti Abiatari àlùfáà àti Joabu balógun, ṣùgbọ́n kò sì pe Solomoni ìránṣẹ́ rẹ.

  3. Màlúù mẹ́wàá tí ó sanra, àti ogún màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti èsúró, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.

  4. Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni a máa ń pèsè màlúù kan, ààyò àgùntàn mẹ́fà àti adìyẹ fún mi àti lẹ́ẹ̀kan ní ọjọ́ mẹ́wàá ni wọ́n máa ń pèsè onírúurú wáìnì tí ó pọ̀ fún mi. Fún gbogbo èyí, èmi kò béèrè oúnjẹ baálẹ̀, nítorí ohun ti a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí pọ̀ jọjọ.

  5. Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà; màlúù pípa àti àgùntàn pípa, ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu! Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu, nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”