Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sheep: Time of shearing, a time of rejoicing

4 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Time of shearing, a time of rejoicing

  1. Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Maoni, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Karmeli; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli.

  2. Ǹjẹ́ ki èmi o mú oúnjẹ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pa fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi sì fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá?”

  3. Abigaili sì tọ Nabali wá, sì wò ó, òun sì ṣe àsè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àsè ọba: inú Nabali sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara; òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀: títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀

  4. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu, Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba.