Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings

802 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ará Ejibiti sì ń lépa wọn, gbogbo ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú òkun.

  2. Ní ìṣọ́ òwúrọ̀ Olúwa bojú wo ogun àwọn ará Ejibiti láàrín ọ̀wọ̀n iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ-ogun Ejibiti.

  3. Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́ ogun náà rìn. Àwọn ará Ejibiti wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá àsálà kúrò ní iwájú àwọn ará Israẹli nítorí Olúwa ń bá wa jà nítorí wọn.”

  4. Olúwa sì wí fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí òkun kí omi òkun lè ya padà sórí àwọn ará Ejibiti, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́ṣin wọn.”

  5. Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú òkun.

  6. Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin: àní, gbogbo ọmọ-ogun Farao tiwọn wọ inú òkun tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yè.

  7. Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli la òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn.

  8. Ni ọjọ́ yìí ni Olúwa gba Israẹli là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti; Israẹli sì rí òkú àwọn ará Ejibiti ni etí òkun.

  9. Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí Olúwa, Èmi yóò kọrin sí Olúwa, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó ti sọ sínú Òkun.

  10. Olúwa ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.

  11. Ológun ni Olúwa, Olúwa ni orúkọ rẹ,

  12. kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú Òkun. Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú Òkun Pupa.

  13. Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta.

  14. “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa, pọ̀ ní agbára. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa, fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.

  15. “Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú. Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ; tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko.

  16. Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun.

  17. Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé, ‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn. èmi ó pín ìkógun; èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn. Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’

  18. Ìwọ fẹ́ èémí rẹ, òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n rì bí òjé ni àárín omi ńlá.

  19. Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, Olúwa? Ta ló dàbí rẹ: ní títóbi, ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn, tí ń ṣe ohun ìyanu?

  20. “Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ si gbé wọn mì.

  21. Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í sákí Ìwọ ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn náà tí Ìwọ ti rà padà. Nínú agbára rẹ Ìwọ yóò tọ́ wọn, lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.

  22. Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì. Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia.

  23. Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu, àwọn olórí Moabu yóò wárìrì. Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù.

  24. Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n, nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta, títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, Olúwa, títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá.

  25. Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n ni orí òkè ti ìwọ jogún, ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa. Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Olúwa.